Háà ! e wo èjè lára Obájolú
….…Dérébà okò nā pápá b’ora
……. Olówò of Òwò,Olíyèré of Ìyèré, Atúlúse Rótìmí Ìbídàpò s’ājò
…….. Wón rān mi n’íbi méédógún (15stiches)
……..Ìyàwó mi bú s’ékún gbaragada
……..Nwón rán etí, ìpempé ojú ati èrèké mi
Obájolú fi èdè abínibí rè (Òwò) bá akòròhìn wa Táíwò Abíódún sòrò
NÍTORÍ ÌKÚNLÈ ABIYAMO Õ
Èjè ńya l’órí , l’ójú, l’étí àti l’érèkē!. Nítorí ìkúnlè abiyamo ò ò! . E wo bí aso funfun báláú ti di pupa l’ówó èjè. Ó dàbí ìgbà tí àwon alápatà bá ńgé eran mààlúù ní àtéńdà. Okò ayókélé ti di okò Owódé Onírin níbi tí wón ti ńta okò tí wón ti ńgé wélé wélé bíi télò (tailor) se ńgé aso .E wo bí iwájú ati èhìn okò ti di búrédì tí a fi owó tè.
”Yépàrìpà kí ló n’selè? . Kí l’ódé? .Tani mo sè ?. Sé èèwò ni kí a tún wá be ilé wò? . Kí ló burú l’áti wá bá won se ayeye ní ìlú tí a ti bí mi? . Sé isé owó àwon òtá ni tàbí àwon ayé?. Lõtó ayé kò f’éni f’órò à fi orí eni”, ni igbe tí arákùnrin Sámúélì Olúwáfémi Obájolú ńké tan tan ti ānú rè sì ńse ènìyàn.
Ó mà se ò! E wo isé owó Dérébà
OJÓ BURÚKÚ ÈSÙ GBOMI MU
Ojó burúkú èsù gb’omi mu ni ojó tí arákùnrin Sámúélì Olúwáfémi Obájolú ti ó ti lo ogbòn odún ni Maryland , America ti o sì tún jé igbá kejì Asojú Omo ìlú Òwò ni gbogbo ilè Amerika,World Council of Òwò Association (WOCOA) fi ara pa nínú ìjàmbá okò ayókélé rè níbi ti ó páàkì rè si tí ó sì ńdúró de òré rè.
Ìsèlè burúkú yìì selè ní ìlú Òwò, ni ìpínlè Oñdó ti a fi orí okùnrin yii s’olè sí . Okùnrin arewà yii ńbò láti ibi tí o ti lo bá won se ayeye ojó àìsùn èye ìkéhìn fun ìyàwó bàbá rè tí ó papò dà l’ójó bi mélo kan séhìn.
Níbi ti arákùnrin Obájolú yìí páàkì okò rè si ti o jókòó sínú rè tí o ńdúró de òré rè ki wón jo padà sí ilé ni okò ayókélé kan ti ńsáré ikú bò ti k’olu okò arákùnrin yìí lójijì láti èhìn. Nse ni Obájolú fi orí so díńgí iwájú tí díńgí èhìn okò náà tún fo lùú, báyìí ni èjè se we arákùnrin Obájolú yìí bí eni tí o sèsè fi omi wè ni balùwè ni. Èrèké, ori, etí àti ìpémpé ojú re fà ya, èjè sì bòõ títí tí aso àlà funfun ti o wò di pupa nitori àgbàrá èjè ti o ñsàn l’órí rè yìí.
Yéè gbèsè ńlá rě
ÌKÀ AWAKÒ SÁ LO
Omo aráíyé mà ní ìkà oo, ìkà sì ni omo aráíyé. Kàkà kí arákùnrin awakò òdaràn yíí dúró wo àláfíà okùnrin tí ó k’olù yìí ñse ni o fi okò ayókélé rè sílè ti o júbà ehoro .Ó fi esè fée. Ìgbé ã fé ewé. Ìsèlè yìí selè ni agogo méwàá k’ojá ìséjú méédógún alé ojó Boxing Day., Osù Òpe, Odún Kérésìmesì ti àwon elésìn Krìsténì l’ódún tó k’ojá.
Sùgbón Obájolú hùwà akoni , pèlú ìróra àti èmí ti o kù nínú rè ni o fi fóònù àgbélówó pe àwon dókítà Federal Medical Center (FMC) ,ó gbìyànjú nínú àgbàrá èjè tí ñsàn l’órí rè l’áti pe àwon Dókítà tí ó ti mò ni ilé ìwòsàn yíí ki wón jòwó gba òun bi bàbá ti ńgba omo rè.
E wo ilà òsángangan l’érèké Obájolú ,èjè ñtú yā l’étí
Nígbàtí Akòròhìn wa fi òrò jomitoro òrò l’énu Okùnrin ti ìjàmbá mótò se yìí nā ni Ilè Améríkà, e gbó àlàyé tí ó se.
ENU ONÍKÀN LA TI ŃGBÓ PÒÓÚN
Tóò, ńwón ni enu oníkàn lati ńgbó pòóún, e jé ká gbó òrò lati enu Obájolú : ”Lati Ìlú Òyìnbó ,Améríkà ni mo ti dé, èmi ni igbá Kejì (Vice President ) World Council of Òwò Association (WOCOA) Atúlúse asojú gbogbo omo Òwò ti o wa ni ilè aláwò funfun, America ni gbogbo àgbáláiyé . Mo wá si ìlú mi, Òwò fun ìdí pàtàkì méta , èkíní láti wáá bá Oba Aláíyélúwà Gbádégesin Ajíbádé Ogúnoyè Ìkéta wa se ayeye òpá àse ti Gómìnà ìpínlè Ondó Arákùnrin Rótìmí Akérédolú fĕ fúnn pe o ti di Oba Aláse ni Ojó Kerìnlá Ojó Àbáméta ti a ńpè ni Sátidé ni Osu Òpe. Ìdí èkéjì ni ti ìyãlé ìyá mi ti a ńse ayeye òkú re ni Ojó kerìndínlógbòn ati ojó ketàdínlógbòn Ojó Etì ati Àbáméta , ìkéta ni ti òré mi Oloye Fúnsó Ògúnlànà ti o ńse ayeye márùndílógbòn odún ti a npe ni Silver Jubilee ti òun ati ìyàwó rè ti se ìgbéyàwó ati ojó ìbí ìyàwó rè ti o pe àádóta odún .Ó se ni l’áánú wípé emi kò lè lo si ibi ayeye méji yi mó àfi ti ayeye ibi ti a ti fún Oba wa Olówò ti ìlú Òwò ni òpá àse nìkan ni mo lo. Se rírò ni tènìyàn, síse ni t’Olórun Oba!.
Ààre Atúlúse Rótìmí Ìbídàpò ati Obájólú ki ìsèlè ìjàmbá okò nā tó selè
”Nípa ti ìpalára ti mo ní, l’ójijì ni mo gbó gbã ti okò ayókéle kan k’olu okò ayókélé ti emi wà ninu rè láti èhìn nígbatí mo ñbo lati ibi aìsùn ayeye ìkéhìn ìyàwó bàbá mi ti èmi ati òré mi Akin Oládiméjì ti o ñwà mi kiri.
Obájolú ati Aláíyélúwà Olówò ti ìlú Òwò ki ìsèlè ìjàmbá okò tó s’elè
ALÁÁNÚ ARÁ SAMÁRÍÀ SEMÍ LÕRE
Pèlú bí wón ti ni ènìyàn búburú pò tó, ñjé é mò pe ènìyàn rere háà tún wà bí?. Níbi tí Obájolú ti npe òré rè dókítà ni arákùnrin kan ti ñje Ògúnmóláwa télè (now Olúwámóláwá) sáré tete wā ba Obájolú lati gbee lo si ilé ìwòsàn, béèni ñwón ñpèé l’ótún àti l’ósì ti won nse aájò rè, o wa dàbí Àre ñwè l’ódò t’omodé t’àgbà ñyowó ose nwípé t’èmi ni o gbà,t’èmi ni o mú. Láì fa órò gùn lo wón gbé mi d’élé ìwòsàn , níbè ni mo rí awon ògbóñtarìgì Dókítà méta ti won ńdu èmi mi. Hã Obájolú ko gbódò ku ni igbe ti won ñké lénu.
Yěpàrìpà okò ti di ti Owódé Onírin
RERE LÓ PÉ
“Njé e mò pé òkúta ti a ba jù síwájú a ó ò tún bãa, rere ló pé ìkà kò pé. Ni òpòlópò ìgbà ni èmi àti àwon èèyàn mi ni ilè America ńkó oògùn, ohun èlò lórísirísi wá si ile ìwòsàn yî nítorí awon ènìyàn wa tí won kò ni ànfàní lati wa gba iwòsàn ni ìlú America. Ni osù Kérin,( Osu Igbe ) odún tó k’ojá ni gbogbo àwa ti a wà ni ìlú America parapò ti a kó àwon aláwòfunfun dókítà onísé abe, Nôsi ati ohun èlòo ati òpòlópò egbòogi wá si ile ìwòsàn yi. Mo rántí Dókítà Oláyíwolá Olágbègí ati Ogbéni Pharmacist Ògúnmóláwá ni ilu St. Louis ,Missourri , ati àwon béèbéè ti wón wá pèlú. Gbogbo àwon dókítà wonyi : Liasu Ahmed, Fasiroti, Oyemolade Ibrahim Taoheed ni wón t’éwó gbàá nígbà nāa, wón dá mi mò dáradára .Nwón gbé mi lo si tíátà ,iyàrá ti wón ti ńse isé abe (theatre) wón si rán etí , ìpémpé ojú ati èrèké mi, èyí so mi di òkolà l’érèké l’ósángagan. ”
Pèlú ìbànújé okàn ni okùnrin náà tèsíwájú ninu òrò rè, o ni “Nwon kò gba owó l’ówó mi rárá, òfé ni won t’ójú mi ní ilé ìwòsàn FMC .Mo si lo ojó mérin gbáko ni ilé ìwosàn yii. Sùgbón sá o l’ójó kejì ìselè yi ,nse ni nwon tún fi okò pàjáwìrì (Ambulance) asáré tete bi àsá ti won fi ñgbe alaìsàn gbé mi lo si Àkúré lati se MRI , awòrán orùn mi ati gbogbo èyà ara mi fún àyèwò fínnífínní bóyá a kìí mò ohun ti o ti s’elè s’inú àgó ara mi. Mo san egbèrún l’ónà ogóta náírà(60,000 naira).
.
Ewà rèé, sùgbón ìyàwó mbe n’ílé o èyin abéléja yán
Mo kúrò n’ílé iwòsàn l’ójó kerin , sùgbón nígbà tí mo wà níbè Oba wa Aláyélúwà Oba Gbádégesin Ajíbádé Ògúnoyè III, Oba Omótúndé Adáko (Olíyèré of Ìyèré), Olóyè Atúlúse ti ilu Òwò, Rótìmí Ìbídàpò ati awon òré ati ará ilé oun ojúlùmò wa bè mí wò. Awon ti kò le wa fi ipè ráñsé.
ÈRÒ MI L’ÁTI TÚ ILÉ ÌWÒSÀN SE SÍI
”Nígbàtí mo wà n’ílé ìwòsàn mo rii pe o ku díè kã to n’ípa ohun èlò irinsé ilé ìwòsàn yìí mo si pinú pé ńgô gbìyànjú lati ra orísirísi ohun èlò si ibè . Emi ni o se l’oni tani a mò ti o máa kàn lóla?.Ňjé mo tilè là àlá pé èmi nã yio je àñfàní gbogbo ohun èlò ti a kó s’ílé ìwòsàn yìí ní kíákíá?. E è wo isé Olórun Oba bí? .Oba àwámáridi .
Háà, ìkà ní Dereba yii
EMI RÈÉ L’ÓWÓ OKO ÀÁRÒ
”Èmi rèé o l’ówó oko àárò. Mo fi ara pípé wá sí ilé mo sì gun kèké aláàbò ara padà si ìlú Òyìnbó , èé ti jé? . Nígbàtí mo dé pápá ìdíkò òfurufú ti Múrítàlá Mohamed ni ìlú Èkó ni wón fún mi ni Kèké aláàbò ara (wheelchair) lati fi se àtègùn sínū bààlúù . Nígbàtí mo tún dé ìlú America kèké kanã ni mo tun lò ni pápá ìdíkò òfurufú won. Gbogbo won lo ñkí mi kãbò, mo kú orí ire.
“Nígbàtí ìyàwó mi gbó, igbe ńlá lo bú si, ó si bú s’ékún gbaragada bī bèbí béèni o si ńgbàdúrà fún mi kíkan kíkan pèlú òpòlópò ãwè. Àwon omo mi kò tètè mo ohun tó s’elè sí mi.
IYÁN OGÚN ODÚN
”O jé ohun ìbànúje àti ìyàlénu fún mi l’ati ríi pé omokùnrin dérébà ti o w’akò ijàmbá yii fi pápá bora. Emi kò gbúró rè títí mo fi padà si ìlú America .Háà! o ti gbàgbé wípé iyán ogún odún a máa ńjó ni l’ówó join join. Omodé bú igi ìrókò o nbu ojú w’èhìn, sé òòjó ló ń’wó pani ni?. Bi mo se ń’sòrò yii okò ayókélé mi náà wà ni àgó olópá. Mo gbó pé àwon ará ilé okùnrin ti o fi okò k’olù mi yii ńwá bèbè l’ódò àwon ènìyàn mi pe omo àwon kò ńmu otí àti pé Ààfáà Mùsùlùmí gidi ni .
”Sùgbón kíni ká ti pe irú èyí?. Efun ni tàbí èdì?. Kí awakò máa sáré máìlì ogórin si ogórún ni ìgboro ìlú? .Ìkà ènìyàn rèé o, t’àbí kíni kí nso?” .