Àjé kó ni mí o

 

…… Wòòlíì so pé  Àjé ni Ì wa——Àwon omo lo so béè

……Èmi kì í se Àjé —–Ìyá f’èsì

………Ìyá  je májèlé , o si kú

OLÓRÍBURÚKÚ NI ÀWON  WÒÒLÍÌ  ÈKÉ WÒNYÍ

Ohun tí àwon Wòòlíì  èké ndá s’ílè  láárín ebí , ará, òré ati ojúlùmò ló  pòjù  . A ni apanimáyodà ni àwon  Wòòlíì èké wònyí o jàre.  Mo tètè maa nbínú o. Ní bí mo se nkòwé yi inú mbi mi, inú mi nhó  bi ose , mo ni inú mi nru bi eni ti o nje fùkù  eran  , sèbí nwon ni eni ba nje fùkù  tiise ara orísirísi inu eran tètè maa nbinú .Mo ni sé inú mi ńru bi omi Òkun.

                        MÁJÈLÉ

       Se e ri awon Wòòlíì wònyí   a bá ni w’óràn bi a kò rí dá ni ńwon. Mo ni sé awon  Wòòlíì  èké wonyi  eni a ńyegi fun ni won  o jàre.    Àni sé nse lo ye ki a so olo mo won l’órùn ki a si jù won s’inú  ògbun àìnísàlè. Mo ni ki a jù won si inú  omi gbígbóná  ti o nho yaa yaa  ki won maa kigbe ”Oroo oooo”.

      Àdúrà mi ni pe ki Olódùmarè ro òjò  eyìn iná  le won l’óri ki won jóná  ráú ráú. Ki won wo iná apáàdì ni ojó  ìkéhìn. Àni se ki won j’aporó ki won to kú . Èyin ènìyàn mi e  gbe ohùn  yin s’ókè ki e ba mi se ààmín lákoláko  ki nmáá gbo ni abúlé  BoN ti mo wa yii.

       MÀMÁ  JE MÁJÈLÉ

       Ó mà se o, e wo màmá ti o nà gbalaja sile yi .Èjè rèé  l’órí ibùsùn tìmù tìmù   . Èjè ree n’ílè , sùgbón o ti dúdú, eyi fihàn pe o ti le to bi wákàtí méta ti òkú yi ti wà n’ílè.  Èjè a ti pò pò mo itó .O n’yotó funfun l’énu. L’óru m’óju yio  ti jà pìtìpìtì bi ejò ágékù ki o to subú s’ílè’ . Yio ti pòkàkà ikú  .Ninú l’ohun ìfun re a ti ge wélé wélé. Béèni èdò ati kíndìnrín re a ti bàjé . Béèni awon kan so pe awon ri l’álé aná . Págà ilè nje ènìyàn.Ki l’óde? Ki ló selè?.

     Ó selè lóótó, kò si iró n’íbè. Mo f’owó sòyà  pà,pà,pà l’éèméta pé ó selè sùgbón kì  í se l’ójú mi o. E  jé ki a bo àwon omo ati ebí rè l’ásírí. Bí a se nkàwé yi , ki okàn  Wòòlíì ati àwon omo màmá yìí  máa ró kì kì kì. Háà èsè nlá  rèé o.

          OHUN Tó SELÈ ̩

   Gégébi ìwádì wa ,  ni odun bi mérin   séhìn ni ìlú ……(A kò ni dárúko rè)Màmá yiì…. ( a kò niì dárúko rè) lo ki awon omo re ni ìlú kan….. (a kò ni dárúko rè). Sugbón rírí ti won rí màmá , nse ni won bèrè si  l’ogun Àjé lee l’órí . Nwón npatewó , wón nhó yèèè, nwón nkígbe ‘ Àjé ni e, iwo ìyá  wa’.

   Kíni èrèdí rè? Nwón ní àbúrò wón tí o ti nse àìsàn l’ójó pípé ni  Wòòlíì   tabi Pasíto Ijo  won so fun won pe ìyá àwon l’o wà nídí òrò yìí.

       LÓDÒ WÒÒLÍÌ  ÈKÉ , ADALÉRÚ

    Léhìn ti Alàgbà Wòòlíì  X ( a fi oruko bò l’ásírí) ké l’óhùn rara pe ‘Jah Eli , Jah Makousa, Jah Jah Jahire, Jah Jakuta,Jah Jafure ,ni eemeta , ni o wa riran oba ògòlò ti o wipe ”Olúwa  wipe  Àjé ni Ìyá yin, àìsàn ti o nba àbúrò yin fíra  wá lati òdò Ìyá yin, nitori náà e lo ro ohun ti e óò se”.

Kíni àwon obìnrin yi gbó  èyí sí ? Wàhálà de! Ìbínú de! . Igbe ” Àséè Àjé  ni Ìyá  wa!” ni àwon obìnrin méjèjì yi fi b’onu. Nígbàtí o di ìròlé nwon ránsé pe ègbón won àgbà lati t’úfò yi funn. Èyí ni o mu ki won bèrè si ba Ìyá won jà n’igbàti o wa si òdò won.

Kíni won gbó béè sí? . Nse ni won ki Ìyá won m’ólè ti won nàá bi ejò àìje. Ará àdúgbò pé lé won l’órí  ibè si kún fófófó bi ojà méta. Kódà bi  abéré bó s’ílè  l’ójó náà l’óhún a ko le rii .Nwon kò tilè jé kí Ìyá sun ilé  won l’ójó náà l’óhún. Láìfa òrò gùn lo títí  òkan ninu ará àdúgbò ni o gba Ìyá won s’ílé  l’álé ojo náà. L’ójó keji Ìyá  padà si ìlú rè .

MÁJÈLÉ

PÁGÀ ÌYÁ JE MÁJÈLÉ

Ìròhìn fi yé  wa wípé , Lójó kéta ti wón s’ílèkùn yàrá ìyá won l’ábúlé ni won ba ri  ìyá ti o ti nà gbalaja s’ílè, ìró ìdí rè ti tú, tòbí lo kù si ìdí rè. Owó  rè òtún lo si apá àríwá , esè rè kan si lo si  ìha gúúsù.  Ìyá ti kú, Ìyá ti gan pa bi eni ti iná èlétíríkì sóókì .Won si bá  ìwé pelebe ti o ko s’ílè  pé  awon omo oun ni o  mu oun  ni àjé.

Sèbí Ìyá na lo si ilé  iwé   ofé  ti Olóògbé  Olóyè Obáfémi  Awólówò da silè ni odun 1955, ni  ori tábìlì rè ni a ti ri ìwé ti fi owó rè  ko bayi  ”Mo gbé egbòogi olóró majèle gamalin ati oògùn òta pìàpìà apeku  je nitori  àwon omo mi pè mi ni Àjé. Sèbí ti n’ba je Àjé n’go ti pa won   je ni kékeré . È̩yin omo ti mo tó d’àgbà, ti mo fi orí gba  àárù fun. L’ójó jíje l’ójó àììje .Se n’ígbà tí e d’àgbà tán ni mo wáá di Àjé. E so fun Pásítò tàbí   Wòòlíì  yin pe ó sé o. Ó dìgbà”.

ARA OMO YÁ 

Tóò ,lehin òpòlópò  àríyànjiyàn  pe ki won gbe aburo won ti ara re ko ya kuro ni abé ààbo  òdo  Wòòlíì lo si ile ìwòsàn. Ni Osíbítùù ni àyèwò èjè ti fi hàn pe arákùnrin  náà  ni àrùn ibà  typhoid.Wón ti tóju rè , ara rè si ti yá.

Sèbí aso kò bá Omóye mó , Omóye sáà ti rìnhòhò w’ojà. Ìyá ti papòdà a sì ti sinn l’ódún náà  l’óhùn. Gbogbo wa l’a sa nlo, àni sé gbogbo wa la je ikú n’ígbèsè nítorípé awáíyé má lo kò sí.Ìpàdé  sì tún di ojó àlùkìámò bi Mùsùlùmí òdodo se nso , ò di ojó àjínde ni Krìsténì nwí.

Mo sèbí eni ti o  so omo rè ni Málomó ndáa inú ara rè ndùn ni, ìgbàwo  ni Málomó   ko niilo?,ìgbàwo ni Mákú ko ni kú o jàre?

Njé ta ló pa màmá?. Sé àwon omo ni tàbí Wòòlíì tàbí májèlé ti o gbé je?

Isèlè yi selè l’óótó  ni ìlú…..Sùgbón a fi orúko bo gbogbo àwon ti òrò yi kàn l’ásírí