…… Wòòlíì so pé Àjé ni Ìyá wa——Àwon omo lo so béè
……Èmi kì í se Àjé —–Ìyá f’èsì
………Ìyá je májèlé , o si kú
OLÓRÍBURÚKÚ NI ÀWON WÒÒLÍÌ ÈKÉ WÒNYÍ
Ohun tí àwon Wòòlíì èké ndá s’ílè láárín ebí , ará, òré ati ojúlùmò ló pòjù . A ni apanimáyodà ni àwon Wòòlíì èké wònyí o jàre. Mo tètè maa nbínú o. Ní bí mo se nkòwé yi inú mbi mi, inú mi nhó bi ose , mo ni inú mi nru bi eni ti o nje fùkù eran , sèbí nwon ni eni ba nje fùkù tiise ara orísirísi inu eran tètè maa nbinú .Mo ni sé inú mi ńru bi omi Òkun.
MÁJÈLÉ
Se e ri awon Wòòlíì wònyí a bá ni w’óràn bi a kò rí dá ni ńwon. Mo ni sé awon Wòòlíì èké wonyi eni a ńyegi fun ni won o jàre. Àni sé nse lo ye ki a so olo mo won l’órùn ki a si jù won s’inú ògbun àìnísàlè. Mo ni ki a jù won si inú omi gbígbóná ti o nho yaa yaa ki won maa kigbe ”Oroo oooo”.
Àdúrà mi ni pe ki Olódùmarè ro òjò eyìn iná le won l’óri ki won jóná ráú ráú. Ki won wo iná apáàdì ni ojó ìkéhìn. Àni se ki won j’aporó ki won to kú . Èyin ènìyàn mi e gbe ohùn yin s’ókè ki e ba mi se ààmín lákoláko ki nmáá gbo ni abúlé BoN ti mo wa yii.
MÀMÁ JE MÁJÈLÉ
Ó mà se o, e wo màmá ti o nà gbalaja sile yi .Èjè rèé l’órí ibùsùn tìmù tìmù . Èjè ree n’ílè , sùgbón o ti dúdú, eyi fihàn pe o ti le to bi wákàtí méta ti òkú yi ti wà n’ílè. Èjè a ti pò pò mo itó .O n’yotó funfun l’énu. L’óru m’óju yio ti jà pìtìpìtì bi ejò ágékù ki o to subú s’ílè’ . Yio ti pòkàkà ikú .Ninú l’ohun ìfun re a ti ge wélé wélé. Béèni èdò ati kíndìnrín re a ti bàjé . Béèni awon kan so pe awon ri l’álé aná . Págà ilè nje ènìyàn.Ki l’óde? Ki ló selè?.
Ó selè lóótó, kò si iró n’íbè. Mo f’owó sòyà pà,pà,pà l’éèméta pé ó selè sùgbón kì í se l’ójú mi o. E jé ki a bo àwon omo ati ebí rè l’ásírí. Bí a se nkàwé yi , ki okàn Wòòlíì ati àwon omo màmá yìí máa ró kì kì kì. Háà èsè nlá rèé o.
OHUN Tó SELÈ ̩
Gégébi ìwádì wa , ni odun bi mérin séhìn ni ìlú ……(A kò ni dárúko rè)Màmá yiì…. ( a kò niì dárúko rè) lo ki awon omo re ni ìlú kan….. (a kò ni dárúko rè). Sugbón rírí ti won rí màmá , nse ni won bèrè si l’ogun Àjé lee l’órí . Nwón npatewó , wón nhó yèèè, nwón nkígbe ‘ Àjé ni e, iwo ìyá wa’.
Kíni èrèdí rè? Nwón ní àbúrò wón tí o ti nse àìsàn l’ójó pípé ni Wòòlíì tabi Pasíto Ijo won so fun won pe ìyá àwon l’o wà nídí òrò yìí.
LÓDÒ WÒÒLÍÌ ÈKÉ , ADALÉRÚ
Léhìn ti Alàgbà Wòòlíì X ( a fi oruko bò l’ásírí) ké l’óhùn rara pe ‘Jah Eli , Jah Makousa, Jah Jah Jahire, Jah Jakuta,Jah Jafure ,ni eemeta , ni o wa riran oba ògòlò ti o wipe ”Olúwa wipe Àjé ni Ìyá yin, àìsàn ti o nba àbúrò yin fíra wá lati òdò Ìyá yin, nitori náà e lo ro ohun ti e óò se”.
Kíni àwon obìnrin yi gbó èyí sí ? Wàhálà de! Ìbínú de! . Igbe ” Àséè Àjé ni Ìyá wa!” ni àwon obìnrin méjèjì yi fi b’onu. Nígbàtí o di ìròlé nwon ránsé pe ègbón won àgbà lati t’úfò yi funn. Èyí ni o mu ki won bèrè si ba Ìyá won jà n’igbàti o wa si òdò won.
Kíni won gbó béè sí? . Nse ni won ki Ìyá won m’ólè ti won nàá bi ejò àìje. Ará àdúgbò pé lé won l’órí ibè si kún fófófó bi ojà méta. Kódà bi abéré bó s’ílè l’ójó náà l’óhún a ko le rii .Nwon kò tilè jé kí Ìyá sun ilé won l’ójó náà l’óhún. Láìfa òrò gùn lo títí òkan ninu ará àdúgbò ni o gba Ìyá won s’ílé l’álé ojo náà. L’ójó keji Ìyá padà si ìlú rè .
MÁJÈLÉ
PÁGÀ ÌYÁ JE MÁJÈLÉ
Ìròhìn fi yé wa wípé , Lójó kéta ti wón s’ílèkùn yàrá ìyá won l’ábúlé ni won ba ri ìyá ti o ti nà gbalaja s’ílè, ìró ìdí rè ti tú, tòbí lo kù si ìdí rè. Owó rè òtún lo si apá àríwá , esè rè kan si lo si ìha gúúsù. Ìyá ti kú, Ìyá ti gan pa bi eni ti iná èlétíríkì sóókì .Won si bá ìwé pelebe ti o ko s’ílè pé awon omo oun ni o mu oun ni àjé.
Sèbí Ìyá na lo si ilé iwé ofé ti Olóògbé Olóyè Obáfémi Awólówò da silè ni odun 1955, ni ori tábìlì rè ni a ti ri ìwé ti fi owó rè ko bayi ”Mo gbé egbòogi olóró majèle gamalin ati oògùn òta pìàpìà apeku je nitori àwon omo mi pè mi ni Àjé. Sèbí ti n’ba je Àjé n’go ti pa won je ni kékeré . È̩yin omo ti mo tó d’àgbà, ti mo fi orí gba àárù fun. L’ójó jíje l’ójó àììje .Se n’ígbà tí e d’àgbà tán ni mo wáá di Àjé. E so fun Pásítò tàbí Wòòlíì yin pe ó sé o. Ó dìgbà”.
ARA OMO YÁ
Tóò ,lehin òpòlópò àríyànjiyàn pe ki won gbe aburo won ti ara re ko ya kuro ni abé ààbo òdo Wòòlíì lo si ile ìwòsàn. Ni Osíbítùù ni àyèwò èjè ti fi hàn pe arákùnrin náà ni àrùn ibà typhoid.Wón ti tóju rè , ara rè si ti yá.
Sèbí aso kò bá Omóye mó , Omóye sáà ti rìnhòhò w’ojà. Ìyá ti papòdà a sì ti sinn l’ódún náà l’óhùn. Gbogbo wa l’a sa nlo, àni sé gbogbo wa la je ikú n’ígbèsè nítorípé awáíyé má lo kò sí.Ìpàdé sì tún di ojó àlùkìámò bi Mùsùlùmí òdodo se nso , ò di ojó àjínde ni Krìsténì nwí.
Mo sèbí eni ti o so omo rè ni Málomó ndáa inú ara rè ndùn ni, ìgbàwo ni Málomó ko niilo?,ìgbàwo ni Mákú ko ni kú o jàre?
Njé ta ló pa màmá?. Sé àwon omo ni tàbí Wòòlíì tàbí májèlé ti o gbé je?
Isèlè yi selè l’óótó ni ìlú…..Sùgbón a fi orúko bo gbogbo àwon ti òrò yi kàn l’ásírí
Your article helped me a lot, is there any more related content? Thanks!
The MCF 10A cells were cultured in DMEM F12 Thermo Fisher Scientific, United States supplemented with 5 horse serum, 20 ng mL 1 epidermal growth factor EGF, 0 where to buy priligy Because when the whole of Europe fell, the British survived and defended the isolated island in the North Sea of Europe, leaving a key forward position for the Allied invasion of Normandy in the how long does ed take to cure future
0025, but with no difference in OS dapoxetina comprar online Synthesis of droloxifene citrate and its new bioactivity