Gbómogbómo gbé omo mi lo

 

 

…….Omo mi méjì pòórá l’ójó kan

…….Èmi kò mo orúko àwon ayálégbé náà

…….Ìyà ñlá jé mí

…..Ólópa tún fi ìyà je mí l’ójó náà l’óhūn

                            
        

     ÌBÊRÈ ÑLA: ÀWON OMÕ MI  DÀ?

           Ekún gbaragada ni abiléko   Bimbo Lékan ti i se   ìyá  olómo méjì  yi bú  sí ti o si ñgbéra sánlè l’ójó Ogbòn, osù Sere, odun 2018 (30-1-2018). Eni tí o ba  ríi yióò sàánū abiyamo  bí ó  ti se ñsokún kíkòrò  lójó nā lóhún. Nítorí náà kò ya n’ilénu nínú ìsesí áti ìhùwàsíi rè  ‘lòdò ìyá  rè àgbà ti Akòròhìn yīi ti bā .Ñse ni ó ñsáré  jáde , tí ó tún ñsare wolé ,ti  ó ńkígbe l’ohun rara ti o sì  ńbèrè pé ”Omo mì dà? omo mì dà?”. Sùgbón kò sí eni ti o le dáhùn ìbere ńla yii .

       Àwon tí kò mo ohun ti ó  dé baa rò pe wèrè ni sùgbón kò ñse wèrè o, nítorí orí rè pé  ju bí wón se ròó lo. Léèkan síi ,jìnnìjìnnì bõ, o tún bérè pe ”Àwon omo mi dà? . Ìyá je mí .Mo r’oko d’élé Dálémo. Agbón ta mí . Mo se oore dáràn. Págà!! , a tii gbó pe  odindi omo méjì põrá ninu ilé ti gbogbo wa wà yi?”.Igbe e ba mi wá omo mi ni arábìnrin yìi wa ńke tòò, ó sì ńgbéra s’áńlè bi  àgékù ejò.

    ” Ó ńta gìrì bi eni ti  àìsan gìrì mú. Ó  ńmí gúle gúle . Ó ñsúkĕ pake pake .Ó  wá  ńwò  bòò  bí  eran  Iléyá . Ojú re  le bi eni ti ó kó àtòsí. Sùgbón kò ya wèrè o, bêni kò sì kó àtòsí. Ìdāmú lo de bā. Sé  eni ti ìdāmu bá dé bá kò sí ohun tí kò le se , kò sì sí  ohun tí kò le so. Òròkórò  ni yio so, ìsokúso ni yio ma jade lenu re  bêni irànrán ni yío o ma se.

Sèbī ìwákúwá la’ñwá ohun tó sonù..        

  Ayòmídé

      Arábìnrin  yii  ñnàgà o ñwa orí tábìlì , ó tún  bèrè mólè o ńwo abé àga, o sáré wo yàrá ó ńye tìmùtìmù  orí ibùsùn wò. Sùgbón  kò ri àwon  omo  rè méjèjì níbè  .Lógán ló bá ráńtí  pé ayálégbé lo ńbá àwon omo òun seré tó  fà wón l’ówó lo tó fē ra sweet fún won .Ahh, níbo ni ó hā lo? .Ó sáré wo yàrá arábìnrin yīi  sùgbón kò si ènìyàn níbè .Ìgbóná ara mū, o sáré jáde  kò mà  ri won  mó!, Omo mi sonù sáà sàn ju omo mi nù lo. ”Bawo ni ki ñse so fún bàbá àwon omo mi méjèjì yī pé àwon omo yìí sonù. áwon ajómogbé lo se ìkà  èyi fun mi?.Omo ò mi dà? ,omo ò mi dà?. Kíni mó se? .Èé tirí? .Iná jómi , wèrèpè bò  mi, agbón ti ta mí o. Ah , ìyà ñlá  ni eléyìí.Ta ni mo sè? .Èbè la ñbe òsìkà ki ó dákun dáríjí ni”, se igbe kíké ni isé eiye, igbe ni arábìnrin yi  ñke tañtañ tan, ti o si ñfi owó lu ògiri bi Bíríkìlà se ñfi òbe ré ilé.

        Ni ojó  òni ,ogbòn ojó ,Osù Séré (January 30) ni o   pe odún mêjì  gbáko ti abiléko ti orúko nje Bímbo Lekan  ti ńwá omo méjèji ti orúko won ńjé Blessing  to wa ni omo osu mejo  ati Ayòmídé Lêkan  omo odun meji le ni osu mejo   ti di awátì ni Ojúlé Métàdínlógbòn Àdúgbõ, Òkèdógbòn  , Ò
       ÒRÒ LÉNU BIMBO
   Pélú omijé  l’ójú  òun òse ni Bimbo fi bá Akòròhìn wa Akòròhìn sòrò l’ójó nā l’óhūn, o ni ”Omo odún méjìlélógún ni mi, isé irun dídì ni mo ko,  Mo bi omo méjì ti won je omo odun méjì ati osu mejo ati àbúrò rè ti o je Omo Osù méjo. L’ójó kan ni omokùnrin kan wá  si ilé wa ni Ojúlé Métàdínlógbòn Àdúgbõ Òkèdógbòn  (27, Òkèdógbòn street) ni ìlú Òwò, lati gba yàrá kan, sùgbón ìyá mi so fun pe  a  kò  le fún okùnrin tííse àpón ní ilê .Okùnrin yìí si padà wa pèlù obìnrin ti o pe ni ìyàwó rè. A ní kí ó san   egbèrún  méjì  naira (2,000) l’ósù sùgbón ñwón bèbè fún èédégbèjo naira (1,500) l’ósù. o san owó ilé a si gbàá s’ílé. Wón san owó odún kan  a kò i tii fún won ni ìwé èrí owo sísan (receipt)  sùgbón l’ójó k’efà ni wón pòórá bí isó ti a kò ri won mó pèlú omo mi méjì.
          Arábìnrin yìí tèsíwájú nínú òrò rè , o ni  ”Ohun tí ó dùn  mí  jù ni pé a kò kò tíì fun wón ni receipt .L’ójó tí wón jí omo gbé yìí arábìnrin ti o p’era rè ni ìyàwó okùnrin yiì gbé omo mi tí o ñsúnkun .Ó si ñba mi d’irun fún èkéjì níwòn ìgbàtí o so pé isé irun dídì ni oun yàn láàyo. l’éhìn èyí o ni oun fé ló ra sweet fun won.Èmi sì ñfõ aso l’ehìnkùnle.
Obìnrin náà tè  síwájú o ni ”Nígbàti mo parí aso fífò mo wá àwon omo mi tì sùgbón ti a wo yàrá obìnrin yìi àpo Ghána Must Go nìkan ni a bá n’íbè , nínú rè ni a ri bébà tií wón ti gé wélé wélé nínú re .
        KO SI ÀWÒRAN ÀWON OMO
    Nígbà tí Akòròhìn wa Táíwò Abíódún bérè àwòrán (photographs) àwon omo méjèjì, nse ni obìnrin yìí ñwò pàkò pàkò bí orí eran ti o so pe òun kò ni àwòran won l’ówó àfi èyí kékeré n’ígbàtí ti o wà ni omo osù méjì’
Ñse ni wón ñsó obìnrin yìí l’ówó l’ésè bí eni ti o ni ode orí n’ígbàtí Oníròhìn wa báa l’ódo ìyá rè àgbà l’ójó náà l’óhūn.
   Ìròhìn tó tè wá l’ówó nīi pé l’áti ìgbà yen   à  kò gbúrõ wípé wón rii  àwon omo mêjì yi ì rárá.
E kò háà ri n’kan bí? .E wáíye obìnrin abiyamo l’óde.
Àdúrà tán n’ílé aládúrà , olópã na ñké tantan ,beni ará àdúgbò ñ’logun .Ìgbàkigbà tí obìnrin yìí ba ji l’órū l’áti fún omo rè l’ómú  ni yíõ tó ráñtí wípé awon omo òun méjiì ti di àwátì.
Awon omo wa kò ni  di àwátì o. E se àmín kí e fi owó àdúrà b’ójú , kí e si fi owo àdúrà s’owó ráñsé si òùnkòwé yìí.  À ní  títí di bí a se ñkòwé yī a kò  gbó nkànkan n’ipa àwon omo méjèjì yīi o.
Sùgbón bí a se ñko ìròhìn yìí Obìnrin yí sì wà l’áíyé ó sì wà l’áàìyè rè o. L’óotóo omo mi kú sàn ju omo mi nù lo bēe si ni   A kò mo ohun Olóun yí oò se  ko je ká b’ínú kú.

NB

E f’arabalè l’á’ti gbó òrò y’oku l’enu arabinrin yi ninu fidio yii