Ojú tì mí, àkààrà tú sé’po

  

    ……Ògbólõgbó olè ni mí télè

    ……Mo dá  omo mi l’ónà

   …… Olóògùn háúnháún ni Bàbá mi

    ……Ní ìdájí ni …

KÉKERÉ LA TIÍ PÈKA ÌRÓKÒ

    Olè ni mí, olè lásán kó o, òfóòn,  jàgùdà páálí bìlísì ni mí.Mo ní a lo k’ólóhun k’ígbe ni mò ñse . Àní sé gbéwiri l’èmi, mo wā di ògbólõgbó ìgáárá olósà títí mo fi dàgbà .Mo bèrè níbi à ñyo eran obè je nínú ìkòkò ìsasùn. Mo  jí salúbàtà nínú Mósálási  ni Ìdúmòtà .Mo ti jí owó Àfáà n’íbi tí wón ti n’somolórúko l’órí pápá bòólù ìseré Sūrulérè. Ni Sòósì Yábá pàápàá mo ti ji owó igbá s’álo ri .S’èbi èmi ni mo kó owó ojú ebo lo ni’joun pèlu owó eyo ni oríta méta l’Ojóta. Nínú Móòluè l’Eko n’kò kìí san owó okò, n’go sì tún yo owó l’ápò àwon ará inu okò .Mo mà j’alè sáyé ò. Sùgbón olè pépèpé ni.

”Sùgbón sá o isé ti a kò gbódò fi yangàn láwùjo ni. Aní se isé ti a kò gbódò gbàá lādűrà fi lé omo l’ówó ni. À ní sé isé àbùkù ni. Béè nínú isé alo kólóhun kígbe yìi mo dúpé pé mo ti fi da ñkan rere gbé se .Tàbí kí le ní kí ñwí o jàre?. Isé sáà ni isé ñje, nitori nínú rè mo ti kó ilé , mo ti fé ìyàwó, àwon omo mi si ti pari Ilé ìwé gíga ti Unifásítì ni ìlú Oyìnbo, mo si ti f’ìyàwó f’ómo, mo f’oko f’ómo, kí ló tún kù?

BÀBÁ MI

   ”Kí ñ’to bèrè ìtàn mi e jé ki ñso n’ipa Bàbá mi ; Olóògùn háúnháún ni Bàbá mi ise, ogbologbo Babaláwo sì ni pèlú. Olóògùn a jé bí i idán ni nítirè, à ni sé Olóògùn pónbélé ni. Tí ó bá ní kí  òru di òsán béè lo máa rí, bí ó sì ní kí  òsán di òru yìí o ri béè náà ni. Dandan sì ni, kò sí àmó àmó níbè .Àwa méta ni bàbá mi bí l’ómo. Kí ó tó kú ni odún 1972 ni o ti kó mi l’óògùn àféèrí,ó sì tún kó mi ni oògùn ayeta nítorí pé o nsisé fún àwon jàgùdà , àwon òsèlú ,sèbí e rántí Operation Wéè ti È ?, àwon jàgídíjàgan, àní sé òun ni o n’sín gbéré fún àwon ti wón n’sisé ìpáñle ni ìdíkò okò akérò . Àwon ti Mushin mòó, ti Oshòdì ,Ojóta ati awon ìdíkò ti o l’órúko L’Ékó mòó. Orúko Bàbá mi ni Máyehùn, àwon kóstómà rè lo fun l’órúko béè o..

”Háà! okùnrin méta ni Bàbá mi íse , béè kò ga púpò, à ní díè ló fi ga ju ìgò bíà lo. Háà lóòtó ni pé ènìyàn kúkurú bìlísì ni , baba nlá bìlísì ni Bàbá mi ise. O gbòwó. O ni òrùka ère, ìgbàdí , ewé njé .Kíni kò ní tán ? Sèbí orísirísi orí là  ńbá ní ìté òkú, orí gbígbe , orí tútù, orí omodé, orí àgbàlágbà  ,orí obìnrin, orí okùnrin , à ni sé Bàbá mi ni oògùn l’ówó, ñse lo máa ñpe òkú seré tí ó sì ñran won n’ísé. Mo gbédí fún Bàbá mi l’órun.

”Sé eni máa  bá Èsù jeun síbí rè a gùn. Nígbàtí Bàbá mi kú mo sá’ré lo kó àwon oògùn níbi ti o fii sí. Sè bi eni bá y’áwó l’ògún ñgbe ,mo tètè  gbée kí ó tó di àwátì , emi kò kúkú jéri enìkànkan nínú wa . Àwon Awo egbé rè  l’ó wá s’ìnkú rè  l’ójó kéta l’éhìn òpòlópò  ètùtù ati ebo.

MO DI OLE

Láì fa  òrò gùn lo títí  mo di adigunjalè mo ñlo àféèrí , mo di ògbólógbò olè, à ni mo di olè háúnháún. Léhìn osù méta owó de, mo ti ra okò ayókélé Mésídīsì , mo fé ìyàwó tuntun ,mo si kó ilé . Ko si ápèje ti n’go ni lo.Mo si ñawo níbi ti mo ba lo. Mò ñse gbajúmò l’ósān alo k’ólóun k’ígbe l’óru. Ni òru n’go di  àhámóra bi eni ti ń’lo ojú ogun sùgbón l’ósán èèyàn gidi ni mi pèlú èrín èye l’énu. Hā! mo di èrù jéjè ajámoláya ,eni à ñsá fún l’óru. Mo di ògbóñtarìgì olè.

 

ÑKAN MÉJÌ L’OBÌNRIN MÒ

 Òré pò jáñtírere, àmó sá ìyàwó mi kò mo isé tí mò ñse, elēhā ni , mo hā. Nkò se ni hã? Àwon obìnrin onítòkítò, wón le sòrò jù òrò fúnra rè lo. Káì  mo tètè gbón , mo sõ di Elēha. S’ebí owó l’obínrín mò, nígbàtí mo  ñse ojúse mi n’ílé ,owó n’ìkan kó o, nkò fi oorun dùnn.Ñkan méjì l’obìnrin mò; agogo abé okùnrin  ati owó. Òun nã ńse ojúse rè fun àwon ebí tírè , kí ló tún kù? .E fìyen s’ílè o jàre.Mo hã .Èyin òñkàwé mí e kò rìì pe inú jin?. Ãh , inú  mà jìn o.

   ISÉ MI

Mo jéjé or n’go jáwó nínú isé olè jíjà  nígbà ti mo bá ti ri  owó tó  mílíónì méjì ,.l’óõoto mo rí to mílíónì méta mo sì jáwó sùgbón a jí ede je kò jí òkan òkan ró. Kàkà kí ñyíwàpadà mo tún tera móó. Sebi  kàkà kí ewe àgbon dè, pípele lo ñpéle sii.Mo padà si èebì mi bi ajá.

ISÉ ÌKEHÌN

  Ni agogo méjì òru ojó kan èmi ati àwon adigunjalè egbé  mi lo j’alè ni Lagos/ Ìbàdàn  express way  a si ri okò ayókélé ti o ñbò pelu obìnrin kan ninu rè. Mo fi gàte mi b’ojú, kíá a ti dá okò dúró, a si ni ki wón s’òkalè. Ni ìséjù àáyá gbogbo nkan inú mótò nã ni a kó ni  àkótán, okùnrin naa sòréndà ara rè mo si gba owo tàbùà tabua l’ówó rè .Sùgbón nígbàti mo nsòrò omokùnrin yìí ñké tan tan béè emi kò dáa l’óhùn. Àwon dánàdánà òré mi si bú s’érin .Èmi naa rii  pé  ohùn arákùnrin yii jo eni mímò sùgbón ñkò lè f’ohùn. Kíni ká ti gbó  pe mo dáa l’ónà?,O ti di isó inú ekú ,àmúmóra ni. Nígbàti o kókó fé lo agídí a fēe fi ìbon tú orí rè ká bi olóde se nfi ìbon tú ori ìkòokò l’óko sùgbón emi a tun pètù fún àwon ìgárá olósà egbé mi pe ki a m’áse ta èjè sílè.

ÀKÀRÀ TÚ S’ÉPO

L’ójó kéta mo wa s’íle, mo si bá omo mi ti o se àlàyé bi olè se dá won l’ónà nígbàti oun ñbo l’ati wa fi ìyàwó àfésónà rè hàn mi .Mo se aájò rè púpò púpò. Mo si bá arábìnrin rè kédùn gidigidi. Sùgbón kini kan s’elè l’ójó kejì.

Ni alé ojó kejì  Àmòké ti íse àfésóna omo mi Káyòdé fe lo se ìgbónsè l’óru ni mo ba fún ni iná  ìléwó àtètàn (torchlight) , o gbaa o si lo si ilé ìgbónsè sùgbón kò dáá pádà. Ni ojó Kejì o tún so pé oun fé se gaa mo bérè l’ówó rè pé  àtètàn àná ñbe l’ówó rè , sùgbón o fi gbígbó se aláìgbó.

 Kò pé  tì mo dé  òdò aláìsàn tí mo lo ki ni ile iwosan nìgbàtí àwon olopá méta wá  pèlú sékésekè esè , ati māmu gāri l’ówó tí wón wa  sí odo òré mi ti won ñbērè  òrò l’ówó rè ,ká tó  wí ká to fò, mo ti pòórá. Èmi kò fe ki enìkéni wá k’óbá mi o jàre. Mo n’pòsé sere , mo wónú okò mo yára kúrò nítòsí ibè .Mo nba ara mi s’òrò nínú mótò pé olòsì l’àwon ti o lo ta àwon olópá l’ólobó. Èèwò a kì i rí iná ní kàñga béèni a ki i rí isó mú . Abéré  á lo kí  òna okùn tó dí.

    ÀSÍRÍ TÚ, ÀKÀRÀ TÚ S’ÉPO

Ni agogo méta òru ni omo mi jí ti o gbé mi k’alè ti o bèrè òrò báyìí ”Bàbá mi kíni dé ti e kò jáwó nínú adigunjalè ti e ti nse bò l’ójó pípé?. Emi ko le so bi ìtìjú yín à ti ti ebí wa i bã ti pò to ti wón ba mu yin mo awon olè l’ójósí”, bi o se nsòrò ni mo nfi agídí ti káfīntà fi nyo ìsó ti mo gbaa lenu re pe ”emi n’jalè? Tútó rè dànù. Nìbô l’o ti ri emi .Àrífín ilé ìyàgbé .Irú kìní òrò burúkú kòbákùngbé wo lo n’so l’énu yii? .Síòo re . Òrò ègbin,òrò òsì. Emi yí óò ta àse fún e bi o ba tún tú òrò rírùn bi isó yi so”, báyìí ni mo se so ti  òun nã dáhùn pé ” Bàbá mi e ni sùúrù”, o si yo fìlà , àtùpà àtètàn l’ówó ati owó j’áde. o ni ” Bàbá mi eyin ni e dá èmi àti ìyàwo mi  l’ónà ti fìlà yin bo sínú búùtù, fìlà naa rèé. Atùpà àtètàn yi le mú nínú mótò mi nígbà tí e da èmi ati ìyàwó mi l’ónà , orúko mi rèe l’ára rè. Aso ti e wò e kò kó won wá’le. E si gbàgbé pe ‘Kòkòrikò le npe òré yin ti oun naa npe yin ni Ikòokò .Ara owó ti e gbà l’ówó mi ni e fún ìyàwó  mi ko fi ra nkan èlò obè ,ti e ba wòó dáradára e óò o ri àmì ìsàmì orúko mi l’ára  rè. Gbogbo rè ni a kó pamó ti e kò mò. Mo si be ìyàwó àfésónà mi ki o s’enu ni ménú.Nígbàti ti e lo j’alè pélú òre yin ni ònà Òrè ni ìbon báá. Òré yin  náà ni  e lo kí ní  ilé ìwòsàn ni àná .Òrê  yin si ti so fún àwon agbófin nigbati e kúro l’ódo rè  tán pe ara yin ni wón nítori naa kí e tètè kúrò ni ilé lo f’ara pamó síbi kan”

Nígbà ti mo gbó òrò yii, jìnnìjìnnì bò mi, ára mí ko l’élè mó. Òógùn bò mi, ara mi tutù ni omi àmù tabi omi àìisì wóta!. L’ábé fáánu ti mo wà ni mo ti nl’àágun fòò,be ni igbé gbígbóná ngbòn mi, ìto tile j’ábó ni abe mi, sokoto mi si tútù lojo naa l’óhūn.Tani irú rè maa se ki o ma di dìndìnrìn?. Kai , àsírí tú, èté  mi de. Mo r’onú títí béè emi ko l’émí lati gbé õgun májèlé je. Emi kò le yìnbon funra mi je.L’òrú ojó náà ni mo gbà ona Bini lo. Ibe ni mo wa titi ti won fi fi ehin òré mi ti àgbá, beeni k’èhìn s’okun ni won nse l’ójó náà lohun”

ÌRONÚPÌWÀDÀ

   ” Mo ti jáwó nínú gbogbo ìwà wònyi. Mo wá lo kó isé Molémolé   ti won npe ni Bíríkìlà .Gbogbo awon omo mi ni o n’ísé l’ówó a fi òkan nínu won ti o fe fi ìwà jo mi, s’èbí eni bí ni l’a njo.Sùgbón ki èsan to ké lé mi l’órí mo ti ke  gbàjawìrì síta pé oun ni omo àbíkéhìn ki o m’ase da l’ásà pe oun féé jo mi .

”Mo ti dàgbà, opélópé  pé ko si aworan fótò nígbà náà l’óhūn, kò sí sí àkosílè fun awon olópá ati èro ayára bi àsá (internet) bi béè kó oká i ba ti fo.Nísisìyí  mo  ti di Pásítò ,mo ńkéde ìwàásù kiri. L’ójó Òsè n’go kó èwu Pásítò wò , n’go máá wàásù l’ori àga ìwàáasù”.

Nse ni kí e paáŕé tí e bá ti gba ohùn mi sílè tán nítorí àwon kan yí óò dá ohùn mi mò”, ni òrò tí  Okunrin yi tè mó wa l’étí.