NÍGBÀTÍ mo pàdé okùnrin nã mo kígbe “Hã mo ti ko Àgbákò!”. Igbe mi sì gba igbó kíkankíkan. Òun naa si dáhùn pé ” Àgbákò ti kò é,o ti fí ojú rī ”.
Ojú sánmà sú dèdè béè sì ni oòrùn ñràn kíkan kíkan. Bí ara mi ti ńgbóná bi eni a d’áná igi fún yá bé è sì ni ó ñ’tùtù bi omi inú fíríjì sùgbón èrù ko bà mi bē sì ni àyà kò fò mi. Sèbí okùnrin ni mi? . Sèbí mo ni gògóngò l’órùn?. Àní se èmi kì ì se okùnrin ojo.
Rírí tí mo ri Okùnrin naa mú mi rántíi ohun ti Bàbá mi, Jóshúà so fun mi nígbàti ti o n’lo oko ode l’áyé ìgbã ni. Ìjúwe abàmì arákùnrin yi wa sí ìrántí fún mi . Bàbá mi so pe ”Bi ìwo bá rí okùnrin olójú méta, tí ó ní apá méfà, esè mérin, ti iná ñjáde l’énu rè bi Sàngó Olúkòso oko Oya , ti o ñju ìrù rè bénbélé bi òbo lágídò, ti ejò ñyo ahón beere l’órí rè , ti itó enu re ñhó bi ose , ti àkèekèé si ñjáde ni enu rè tó ba ñ’sòrò, ti ìka owó rè ñ’tan iná , ti paramólè ñyojú l’ójú ojúgun esè rè, ti ìgbonsè ñjáde l’étí re, ti o ñyàgbé s’ára sùgbón ti ìgbé rè jé kìki ata àti ìdin , Àgbákò l’o rí yen , sá fūnn. Má se dúro ìwo omo mi. Inú Igbó BoN l’o ñgbé.
Kíámósá mo múra ogun .Mo tú fìlà mi dé , mo si ko iwájú rè si èhìn. Mo fi d’ígí abàmì si oju ti o fi jé pé okùnrin naa ko mo pe ojú mi ti yípadà ,ó ti di pupa bi eyìn iná , èjè si njade l’ójú mi o si ñkán tó, tó tó. Ojú mi ñsáná sàrà sàrà bí àrá l’ójú àwosánmà nígbà òjò.
Ojó l’ojó nã l’óhūn ti mo paradà ti mo di eni a kò gbódò jí rí. Àni sé ojó l’ojó nã l’óhūn ti mo paradà di eni a kò gbàdúrà kí a kò l’ónà oko t’àbí l’ónà ojà . Mo fi òrùka máyehùn si owó sùgbón mo gbàgbé l’áti fi òrùka Kìnìún oníde ti eye abàmì fun mi l’ójósí si íka owó mi lati mò bóyá ewu wà l’ónà. Hã nígbàyìí ni mo tó mò pé ewu wà l’ónà. Èmi Okùnrin méta. Èmi naa Ewu . Ewu ñbe Lóngé, Lóngé pãpã ewu. Èmi oko Rónì, èmi oko Fèróníkà. À ní sé èmi ni eni kòō kò mò ón, eni mò ón kò kò ó.
Mo fi ègbà oníde si owó ti yio mã bá mi s’òrò bi ènìyàn . Beeni n’kò gbàgbé ègbà orùn ti a fi odindi eyín erin ati eyin àmòtékùn àti èdo igi Màhógánì ati ti Ìrókò se.
Bi mo ti k’ojú ìbon mi si okùnrin naa ni o k’ígbe l’óhūn rara pe ” Mo rí e , abàmì okùnrin, mo rí e o Bobo T, T Bobo, BoN, Babalawo Of the Nation, Bàbá olórùka ,ju ìbon re d’ànù , iná mō o l’óní.
Àwa méjèjì fi ìjà peéta. Ìjà nã pò gidigidi l’ójó naa. Nígbàtí Okùnrin Àgbákò yi rii pe owó òun ko bà ‘mi ati pe nkò bìkítà, o fé atégùn si owó re òjò bèrè sii rò , bi òjò se ñrò ni egungun rè ñle sii. Sùgbón mo pe Ìya mi l’órun mo ni ” ìyá mi tōto, abiyamo kìì gbó igbe omo rè ki o mã t’ara, Oládoyin má se wò mi níran . Abiyamo tōto o d’owó re o”.
Mo wo òkè mo wo ilè , mo rañtí wipe òrùka mi àti ògèdè mi ko nii s’isé l’áì fi orúko Olúwa sii. Mo ráñtí pé enìkan tun ñbe ti o ju Bàbá ati Ìyá mi lo. À ní sé , mo ráñtí pe oògùn kò nii je láì fi ti Elédùmarè siii. Ni ìséjú aáya mo kúnlè, mo pe Elédùmarè ti o da ewé ati egbò ki o se àtìlehìn fun mi.
Bí mo se ñse èyí èrín ni ebora ti nwón npè ni Àgbákò bú sí.
( Coming out soon in my Book)
O ku ise takuntakun .Olorun Eledumare a tubo ma a fi ogbon kun ogbon e o. Welldone! May God continue to increase you in wisdom and knowledge.
A dupe ma. E ku ife.