Ògbólóògbó olè ni mí télè

   

    ……Ògbólóògbó olè ni mí télè

    ……Mo dá  omo mi l’ónà

   …… Olóògùn háúnháún ni Bàbá mi

    ……Nnkan méjì l’obìnrin mò

  Bàbá àgbàlagbà yi so ìtan  ìgbesí aíyé rè ki o to  jáde l’áyé  l’ósè tó kojá 

KÉKERÉ LA TIÍ ŃPÈKA ÌRÓKÒ

         O ni mí, olè lásán kó o, òfúnàn  jàgùdà páálí bìlísì ni mí.  Mo ní a lo k’ólóhun k’ígbe ni mò ńńse . Àní sé gbéwiri l’èmi, mo wā di ògbólóògbó ìgáárá olósà títí mo fi dàgbà . Mo bèrè n’íbi à ńyó eran obè je nínú ìkòkò ìsasùn. Fífi ayédèrú kókóró sí àpótí ìfowópamó  . Mo nlo Bárékè  śójà lati j’alè. Mo   ńjí sálúbàtà nínú Mósálási  ni Ìdúmòtà .Mo ti jí owó Àfáà n’íbi tí wón ti ń’se súná omo tuntun l’órí pápá bóòlù ìseré Sùúrulérè, ni Èkó. Ni Sòósì, ilé ìjósìn Olórun ti o wà ni  Yábá pàápàá mo ti ji owó igbá s’álo rí. S’èbí èmi ni mo kó owó ojú ebo lo ni’joun pèlu owó eyo ni oríta méta l’Ójóta .Ni roundabout Mókólá ,Ìbàdàn mo  fi adìye ti won fi ru  ebo pèlú epo pupa ti a dà le l’órí s’ebè ata díndín. Kai!  àfowórá mi pò ki nmá puró. Nínúu Móòluè l’Èkó n’kò kìí san owó okò, n’go sì tún yo owó l’ápò àwon ará inu okò móòlùè , ngóò sì tún máa bá won kédùn. Mo mà j’alè sáyé ò. Sùgbón olè pépèpé ni o.

”Sùgbón sá o isé ti a kò gbódò fi yangàn l’áwùjo ni. Aní se isé ti a kò gbódò gbàá l’ádúrà fi lé omo l’ówó ni. À ní sé isé àbùkù ni. Isé ìtìjú ni pèlú. Sùgbón o ni l’áti gbóyà bii kìnìún ki o si yára bi àsá ninu olè jíjà.  Béè nínú isé a lo k’ólóhun kígbe yìí mo dúpé pé mo ti fi da nnkan rere gbé se láyé  .Tàbí kí le ní kí nwí o jàre?. Isé sáà ni isé nje. Tàbí e rò pe ó r’orùn l’ati j’alè ni?. Mo ti fo ìgànná ti àfókù ìgò ya àwòrán si mi l’ára  yánma yànma  ti èjè si ntú jáde bi omi  èro . Mo ti fi orí ko Ilé agbón ti agbón si t’amí l’áta d’ákú. Mo ni iná èlétíríkì ti sóòkì mi ri tí  báábù wayà si ti fi ya máápù  Áfíríkà si mi l’ára.    Àní gbogbo ara mi kìkì àpá ni. Nínú olè jíjà yi ni mo ti kó ilé , mo ti fé ìyàwó, àwon omo mi si ti parí Ilé ìwé gíga ti Unifásítì ni ìlú Òyìnbó. Mo sì ti f’ìyàwó f’ómo, mo si f’oko f’ómo, kí ló tún kù?

Táíwò Abíódún l’órí ìrìn àkòròhìn

BÀBÁ MI

   ”Kí n’to bèrè ìtàn mi e jé ki nso n’ipa Bàbá mi: Olóògùn háúnháún ni Bàbá mi íse, ògbólóògbó Babaláwo sì ni pèlú. Olóògùn a jé bí i idán ni nítirè, à ni sé Olóògùn pónbélé ni. Tí ó bá ní kí  òru di òsán béè lo máa rí, bí ó sì ní kí  òsán di òru yì oò ri béè náà ni. Dandan sì ni, kò sí àníàní níbè .

”Àwa méta ni bàbá mi bí l’ómo. Kí ó tó kú ni odún 1970 ni o ti kó mi l’óògùn àféèrí. Aáyán, ìmí ojó, orí ìjímèrè ati ehín oká pèlú awon  èròjà míràn la fi se é. Ó sì tún kó mi ni oògùn ayeta nítorí pé o ńsisé fún àwon jàgùdà  àti àwon òsèlú .Sèbí e rántí Operation Wéètì è àti ogun àgbékòyà?, àwon jàgídíjàgan, àní sé òun ni o n’sín gbéré fún àwon ti wón ń’sisé ìpánle ni ìdíkò okò akérò . Àwon ti Mushin mòó, ti Oshòdì ,Ojóta ati awon ìdíkò ti o l’órúko L’Ékó mòó. Orúko Bàbá mi ni Máyehùn, àwon kóstómà rè lo funn l’órúko ìnàgìje yìì  o.

”Háà! okùnrin méta ni Bàbá mi íse , béè kò ga púpò, à ní díè ló fi ga ju ìgò bíà lo. Háà lóòtó ni pé ènìyàn kúkurú bìlísì ni , baba nlá bìlísì ni Bàbá mi īse. O gbówó. O ni òrùka ère, ìgbàdí , ewé njé .Kíni kò ní tán ?. Sèbí orísirísi orí là  ńbá ní ìté òkú, orí gbígbe , orí tútù, orí omodé, orí àgbàlágbà  ,orí obìnrin, orí okùnrin , à ni sé Bàbá mi ni oògùn l’ówó, nse lo máa npe òkú s’eré tí ó sì nran won n’ísé. Mo gbédí fún Bàbá mi l’órun.

”Sé eni máa  bá Èsù jeun síbí rè a gùn. Nígbàtí Bàbá mi kú mo sá’ré lo kó àwon oògùn rè níbi ti o ko won   sí. Sè bi eni bá y’áwó l’ògún ńgbè ,mo tètè  ko won  kí ó tó di àwátì .Emi kò kúkú jéri enìkànkan nínú àwa omo rè. Àwon Aláwo egbé rè  l’ó wá s’ìnkú rè  l’ójó kéta  ti o ti papòdà   l’éhìn òpòlópò  ètùtù ati ebo.

MO DI OLÈ

   ”Láì fa  òrò gùn lo títí  mo di adigunjalè mo nnlo àféèrí , mo di ògbólóògbò olè, à ni mo di olè háúnháún. Léhìn osù méta owó dé, mo  ra okò ayókélé Mésídíìsì , mo fé ìyàwó tuntun ,mo si kó ilé . Ko si ápèje ti n’kò kìí lo. Mo si nnawo  bi elédà níbi ti mo ba lo. Mò nnse gbajúmò l’ósán alo k’ólóun k’ígbe l’óru. Ni òru n’go di  ìhámóra bi eni ti ń’lo ojú ogun sùgbón l’ósán èèyàn gidi ni mi pèlú èrín èye oun òyàyà l’énu. Háà! mo di èrù jèjè ajámoláyà ,eni à ńsá fún l’óru. Mo di ògbóntarìgì olè.

 

NNKAN MÉJÌ L’OBÌNRIN MÒ

    ”Òré mi pò jántírere, àmó sá ìyàwó mi kò mo isé tí mò nse, eléèha ni , mo háa. Nkò se ni háa? Àwon obìnrin onítòkítò, wón le sòrò jù òrò fúnra rè lo. Káì  mo tètè gbón , mo so o di Eléha. S’ebí owó l’obínrín mò, nígbàtí mo  nse ojúse mi n’ílé ,owó n’ìkan kó o, nkò fi oorun dùnn. Nnkan méjì l’obìnrin mò: agogo abé okùnrin  ati owó àpèkánukò. Òun náà ńse ojúse rè fun àwon ebí tírè , kí ló tún kù? .E fìyen s’ílè o jàre. Mo háa .Èyin ònkàwéè mi e kò rìì pe inú jìn?. Háà , inú  mà jìn o.

   ISÉ MI

       ”Mo jéjé  pe  n’go jáwó nínú isé olè jíjà  nígbà ti mo bá ti ri  owó tó tó mílíónì méjì  náírà .L’óòótó mo rí to mílíónì méta mo sì jáwó sùgbón a jí ede je kò jí òkan  ró. Kàkà kí nyíwàpadà mo tún tera móó. Sèbí  kàkà kí ewe àgbon dè, pipélé lo ńpélé sii. Mo padà sí èebì mi bí ajá.

ISÉ ÌKÉHÌN

      Ni agogo méjì òru ojó kan èmi ati àwon adigunjalè egbé  mi lo j’alè ni  òna márosè Lagos/ Ìbàdàn    a si ri okò ayókélé ti o ńbò pèlú obìnrin kan nínú rè. Mo fi gàte mi b’ojú, kíá a ti dá okò dúró, a sì ní  kí wón s’òkalè. Ni ìséjù akàn gbogbo nkan inú mótò náà ni a kó ni  àkótán. Okùnrin náà sòréndà ara rè mo si gba owo tàbùà tabua l’ówó rè . Sùgbón nígbàti mo nsoro l’ówó omokùnrin yìí nké tan tan ó sì ńlo agídí béè emi kò dáa l’óhùn. Àwon dánàdánà egbé mi sì bú s’érín .Èmi náà  ríi  pé  ohùn arákùnrin yii jo eni mímò sùgbón nkò lè f’ohùn. Kíni ká ti gbó  pe mo dáa l’ónà?, òràn ti di isó inú èkú ,àmúmóra ni. Nígbàti o kókó fé lo agídí a féé fi ìbon tú orí rè ká bi olóde se nfi ìbon tú ori ìkòokò  ati ìtùukù l’óko sùgbón n’go  tun pètù fún àwon ìgárá olósà egbé mi pe ki a m’áse ta èjè sílè.

ÀKÀRÀ TÚ S’ÉPO

     ”L’ójó kéta ni mo wá s’íle, mo  bá omo mi ti o se àlàyé bi àwon  olè se dá won l’ónà Eko si Ibadan  nígbàti oun ńbò l’ati wa fi ìyàwó àfésónà rè hàn mi .Mo se aájò rè púpò púpò. Mo si bá arábìnrin rè kédùn gidigidi. Sùgbón kini kan s’elè l’ójó kejì.

Ni alé ojó kejì  Àmòké ti íse àfésóna omo mi , Akin fe lo se ìgbónsè l’óru ni mo ba fún ni iná  ìléwó àtètàn (torchlight) , o gbàá o si lo si ilé ìgbónsè sùgbón kò dáá pádà. Ni ojó kejì o tún so pé oun fé se gaa mo bérè l’ówó rè pé  àtètàn àná nbe l’ówó rè , sùgbón o fi gbígbó se aláìgbó.

 Kò pé  tì mo dé  òdò aláìsàn tí mo lo ki ni ilé ìwòsàn nìgbàtí àwon olópá méta wá  pèlú sékésekè esè , ati máámu gààrí l’ówó tí wón wa  sí òdo òré mi ti won ńbérè  òrò l’ówó rè ,ká tó  wí ká to fò, mo ti pòórá. Èmi kò fe ki enìkéni wá k’óbá mi o jàre. Mo n’pòsé sere bí ejò , mo wónú okò mo yára kúrò nítòsí ibè .Mo ńbá ara mi s’òrò nínú mótò pé olòsì l’àwon ti o lo ta àwon olópá l’ólobó. Èèwò a kì i rí iná ní kànga béèni a ki i rí isó mú . Abéré  á lo kí  òna okùn tó dí.

    ÀSÍRÍ TÚ, ÀKÀRÀ TÚ S’ÉPO

Ni agogo méta òru ni omo mi jí mi ti o gbé mi k’alè ti o ńbérè òrò báyìí ”Bàbá mi kíni dé ti e kò jáwó nínú ìwà  adigunjalè ti e ti ńse bò l’ójó pípé?. Èmi ko le so bi ìtìjú yín à ti ti ebí wa i báá ti pò to ti wón ba mu yin mo awon olè l’ójósí” .Bi o se nsòrò ni mo nfi agídí ti káfíntà fi ńyo ìsó ti mo gbaa l’énu rè pe ”èmi n’jalè? Tútó rè dànù. Níbo l’o ti ri èmi?. Àrífín ilé ìyàgbé .Irú kìní òrò burúkú kòbákùngbé wo lo n’so l’énu yìí? .Síòo re . Òrò ègbin oníyòrò, òrò òsì. Emi yí óò ta àse fún e bi o ba tún tú òrò rírùn bi isó yi so”. Báyìí ni mo se so ti  òun náà dáhùn pé ” Bàbá mi e ni sùúrù”. Ó sì  yo fìlà , àtùpà àtètàn l’ówó ati owó j’áde. o ni ” Bàbá mi eyin ni e dá èmi àti ìyàwo àfésóná mi  l’ónà ti fìlà yin bó sínú búùtù okò mi, fìlà naa rèé. Àtùpà àtètàn yi le mú nínú mótò mi n’ígbà tí e da èmi ati ìyàwó mi l’ónà , orúko mi rèe l’ára rè. Aso ti e wò e kò kó won wá’le. È sì gbàgbé pe ‘Kòkòrikò le ńpe òré yin ti oun naa npe yin ni Ìkòokò .Ara owó ti e gbà l’ówó mi ni e fún ìyàwó  mi ko fi ra nkan èlò obè ,ti e ba wòó dáradára e óò  rí àmì ìsàmì orúko mi l’ára  rè. Gbogbo rè ni a kó pamó ti e kò mò. Mo si be ìyàwó àfésónà mi ki o s’enu ni ménú. Mo s’èbí ilé eni l’ati ńje èkúté onídodo. Nígbàti ti e lo j’alè pélú òre yin ni ònà Òrè ni ìbon báá. Òré yin  náà ni  e lo kí ní  ilé ìwòsàn ni àná .Òré  yin si ti so fún àwon agbófinró nígbàti e kúro l’ódo rè  tán pe ara yin ni wón nítori náà kí e tètè kúrò ni ilé lo f’ara pamó síbi kan”

Nígbà ti mo gbó òrò yii, jìnnìjìnnì bò mi, ára mí ko l’élè mó. Òógùn bò mi, ara mi tutù bí  omi àìisì wotà !. Mò sì  n’làágùn fòò l’ábée  fáánu ti mo wà  béè  si ni  igbé gbígbóná ngbòn mi, ìto t’ile j’ábó ni abé mi l’óru ojó nā tí sòkòtò mi si tútù l’ojó naa l’óhūn.

Tani irú rè maa se ki o ma di dìndìnrìn?.Mo di òdè. Mo ńwí bótobòto. Òrò mi kò jora won mo .Kai ! , àsírí tú, àkàrà tú s’épo. Èté  mi de. Mo r’onú títí béè èmi ko l’émí lati gbé  májèlé je. Èmi kò le yìnbon funra mi je. L’òrú ojó náà ni mo gbà ona Bìní  lo. Ibè ni mo wà títí ti wón fi fi èhìn òré mi ti àgbá, beeni k’èhìn s’ókun ni won ńse l’ójó náà l’ohun”

ÌRONÚPÌWÀDÀ

   ” Mo ti jáwó nínú gbogbo ìwà wònyí. Mo wá lo kó isé Molémolé   ti won ńpè ni Bíríkìlà. Gbogbo àwon omo mi ni o n’ísé l’ówó a fi òkan nínu won ti o féé  fi ìwà jo mi, s’èbí eni bí ni l’a ńjo. Sùgbón ki èsan to ké lé mi l’órí mo ti ke  gbàjawìrì s’íta pé kí  omo àbíkéhìn  m’áse da l’ásà pe oun féé jo mi .

”Mo ti dàgbà , mo ti le l’ogórin odun, opélópé  pé kò si àwòrán fótò nígbà náà l’óhūn, kò sí sí àkosílè fun awon olópa ati èro ayára bi àsá (internet) bi béè kó oká i ba ti fo. Nísisìyí  mo  ti di Pásítò ,mo ńkéde ìwàásù kiri. L’ójó Òsè n’go kó èwu Pásítò wò , n’go máá wàásù ihìnrere ati ìpadàbo Jéésù l’ori àga ìwàáasù”.

Táíwò Abíódún l’órí ìrìn àkòròhìn

E jòwó nse  ni kí e paáŕé tí e bá ti gba ohùn mi sílè tán nítorí àwon kan yí óò dá ohùn mi mò”, ni òrò tí  Okùnrin yi tè mó wa l’étí.Okùnrin naa ti ta t’éru n’ipa ni  òsè  to k’oja .A fi oruko bòó l’asiri.