Ariwó ta gèè

 

Ni agogo méwá ku ìséjú méjo alé

Ariwó  ta gèè.  Elékún ńsunkún. Àwon abánikédùn  ngbéra s’ánlè  ńwón   ńyí  gbirigbiri n’ílè bi bóòlù aláfesègbá  béè sì ni àwon abánikédùn kan si ńgbé  ara won sánlè  bi ejò  ti wón fi òpá pa  ti o nta ràì  ràì  ti o sì ńjanr’arè m’ólè  .

    Kàkà kí ojó yìí  jé ojó ayò  ojó ìbànújé ni ojó yi ńse. Bi  àwon Obìnrin   se ńtú gèlè ti wón  ńfa irún orí won tu   tí omijé ojú won sì  ńwe  àtíkè nù béèni  àwon  okùnrin nsí fìlà  ti won fi ìka s’enu ti wón  nmí orí  pèlú  ìkáánú béè ni  àwon kan gbá orí mú  ti won ń’fesè jan’lè ti won ń’tu itó sààrà bi  aláboyún  ti kò je àsèje rè. Àwon kan nmi orí won  nwon si ńse aájò won si  ńkan orí m’ólè bi òmùtí  tí o  mutí yó  ti o jóòko l’órí àga béè  won ńkédùn ni o.

Sùgbón  t’àwon kan  wáá pelékè, t’iwon  wáá di  gbà ràn mí d’elérù, wò sò d’èmí  d’oní sò. Eni ti a f’òrò lò t’óní t’òun bàjé , kíní k’ólórò kó se? .Òtò l’eni a gbá l’étí òtò l’eni t’étí ńdùn.  Àsèjù pò. Ìkáánú èké  pò. Sùgbón ó n’ídi ,àní  ti ko ba ni ìdí   obìnrin kì í jé Kúmólú. Àní t’iwon wáá ga jù , àgàgà òré Bàbá ìyàwó ti ó ń’wolé ,ti ó ń’wòde n’ílé  òré rè béè iró la ba n’ídí rè. Bi àwon kan se ńwo òkú n’ílè nínú àgbàrá èjè ni  won  n’fi owó bo imú  ti won si ńtu kèlèbè jáde l’énu  . Béè sì  l’àwon kan ńké ti wón k’áwó l’órí ti won si fi èpè b’onu pé  ”Ení se eléyìí kò  níí  jèrè” . Àwon àgbàgbà Ààfáà Mùsùlùmí ti irun  orí won  funfun báláú ti abe ìfárungbòn  ti kan wón l’órí bi odún méwàá s’éhìn   ńse ”Alhamudu lahi, Allah fun wa o si gbàá lo. Ó yé Olóun”.

Bi ikun imú  ìyá   ìyàwó  ti  nsàn ni o ńgbá ori rè  mú ti o  ńké pe orí òun burú ti o si  ńpòsé   bi ejo sèbé. Ekún ni o ńsun ti o si ńké l’óhùn rara pe ”tani mo sè?. Ta lo s’eka eyi ?”

   È é  tijé ?.Kí l’ódé?. Ní ìséjú aáyá yi? .Aso ìgbéyàwó  ti òyìnbó ni o sì wa l’ára Omolará ti o kún fún kìkì èjè. Ki lo s’elè?.Tani wón sè?.

Bi nwon ti se ńse  aájò l’ówó, ni Bàbá ìyàwó  súré  mu ańkasíìfù funfun báláú wo yàrá lo. Kò sí eni ti o rii. Kíákíá ni o tún bó si ìta. Àwon tí nwón ńse aájò ńse aájò . Kí ló de ti a fi òbe gún arábìnrin yi?. Èsè wo ni o sè?. Ta si ni  òdáràn? Òrò yi ni àwon abánikédùn  ńbérè. Béè si ni oko ìyàwó ńso òyìnbó ti o  bo kóòtù ati  táì orùn  rè  ti o ńtéwó  pè é bi álábòsí obìnrin  ti o ńso oyìnbó pàrà pé  ”O! màì Góòdù. ”

Háà! l’ójó ìgbéyàwó Bàbá ìyàwó fi ilé pon otí o fi ona ro okà. E wá wo orísirísi oúnje ,otí elérindòdò, oti oyìnbó lo súà . Emu ńru fùù bi itó akíwárápá abi itó funfun l’énu.

“Ara ńfu mi ,mo la àlá burúkú kan” , Mama Omolará ni o so fun oko re nipa àlá ti o lá. “Olowo ori mi  jòwó  m’áse je ki a se ìgbéyàwó àwon omo yi nísisìyí”, bi Sade ìyàwó  Dayò  se so fún oko rè nìyen. Sùgbón  Dayò f’esi  ”owo wà, a ó o se ìyàwó yi . A ti dá ojó, a si ti dá osù .A  ko lè yèé mó.  Sèbí owó la féé ná”. Háà owó l’obìnrin mò, bi Sadé se gbó pé owó wà yi , ojú rè padà, o bú rérín  músé bi eni ti o je tété . Ó tú aso ìdí rè ró bi obìnrin ti o nfi ète ńpe oko re s’ínú ìyèwù l’ati wá báa se  yùnkéyùnké . Ó bèrè sii se òyayà , ara re sì yá gágá. Káì , owó àpèkánukò. Owó ni ti oun ko ba si n’ile ki enìkéni m’ase d’ámòràn l’éhìn  oun. Ohun ti owó bá se tì ilè lo n’gbé. Sebi òràn ti owó máaa dá s’ilè kò se é so. Owó dé, ìdùnnú de.

Táiwò Abíódún àkòròhìn  wà ni àsèye kan

          Yorùbá bò won ni gbajúmò kì í wá  ńkan tì,  béè àwári l’obìnrin ńwá nkan obè.  Sadé   lo si ìlú Switzerland lo kó aso olówó iyebíye bi  guinea  brocade alágo ńlá, aso àtíkú ati àwon aso léèsì olówó iyebiye  ti awon kan fi se egbéjodá.  Sèbí gbajúmò ni Sadé ńse, eni igba ojú mo , t’irè ti è ju igba ojú mò lo pàápàá. L’ójó ìgbéyàwó Omolará  aso orísiríri lo y’ojú  sèbí orísirísi òbe làá ńrí l’ójó ikú erin. Elégbéjodá lo jántìrere. Owó d’ára òré mi , waa wo góòlù,fàdákà ati díámóndì olówó iyebíye  ti awon ènìyàn fi se èsó. Ha, owó mà dara o , bi o bá ni owó l’ówó ìwo lè fé aya Oba. Sèbí  o ri béè l’ójó náà l’óhùn ti olówó kan ni ilè wa yi fé ìyàwó oba ti gbogbo ìwé ìròhìn gbée jáde. Àní sé ki Oluwa máa se fi owó k’éhìn òrò wa. Mo  ni kí owó ki o m’áse  wón wa, tó tó funn ,owó àpèkánukò. Owó ní í mu àbúrò pe ègbón rán n’ísé . Owó lè je ki omo pe Bàbá ni my padi. Èsù l’owó. Owó a máa mú ni sìse á sì máa mu ni sì òrò so,sùgbón gbogbo ènìyàn kó o.  Owó a maa já itìjú kúrò l’ára eni. Eni bá so pé owó kò d’ára ki o tó ìyà tálákà wò fún odun méta  yióò rí ìyàtò rè.

Oko ìyàwó ńkó? Ségun ti isé  oko ìyàwó ti jáde n’ílé ìwé gíga ti Fásítì, ti o gba oyè Olùkóni  o si ti se odún kan ti Agùnbánirò  ti  o fi sin ìjòba ti a npè ni NYSC . Sùgbón l’éhìn odun k’éfà kò si isé . Bàtà ti yè gèrèrè , okùn rè si ti ńjá, abé re ti lá béè ni aso rè mo orukó orísirísi ose ti a fi ńfòó béèni apá kan ti sá t’orí ìyà ti jeé l’ówó oòrùn. Ségun kò n’ísé l’ówó nse ló ńbá wón ta ayò olópón  l’ábé ìdí igi isin. Ìhàhín lo fi se ibùjóko l’ati máa fi pa ìrònú ré. Ségun mo ayò ti yióòo je,oun naa lo mo ìtàn gbogbo ìlú won. Sèbí n’idi ayò l’ati ńgbo orísirísi òrò , òfófó àti ohun to  ń’selè ni ìlú.  Ségun lo mo àwon ti wón ńyan àlè, òun ni o  mo omo  àle ni ìlú. Àni se  o mo ìgbàtí Òyìnbó Oba obìnrin  Elizabeth ìyá Charlie  ti  ilu  ígíláńdì ti o ta t’éru nipa níjósí gun ori àga àléfà rè . Ségun mo ìgbàtí Elizabeth wa si ìlú Nigeria . Ìtàn ni Ségun mo béè l’órí àìnísélówó  yi náà ni.

 OLÓLÙFÉ MÉJÌ PÀ

Nígbàti Omolará pàdé Ségun, Omolará fíi l’ókàn balè pe oun ó ò  báa wa isé , ati pe Bàbá òun miloníà ni. Haa , tálákà kò d’ára o, abájo ti  abé olówó ni tálákà máa kú si . Sùgbón òfé a mááa pa ènìyàn. Sèbí okùnrin kan l’o kóó si ara okò  re l’ójósí pe ”Òfé ńpa ènìyàn”. A séè ìfà náà a máá fa ni l’áso ya, òfé òun ìfà  omo ìya  ni won . Sèbí eni sè’gbònsè s’ónà dandan ni ko ba esinsin l’ónà to ba ńpadà bò. Ènìyàn to fé omo ni ijù dandan   kó jé   àna ànjònú. Bi tálákà ba múra òfégè tan a ye wón nínu aso iyebíye , won a wa góòlù s’órùn , won a fi fàdákà oun ìlèkè olówó iyebíye s’ówó béè ni won a maa w’òhín w’òhún ki a maa baa jáa gbà. Ani won ko gbódò ta epo si aso won . Bí béèkó won a so oun ti won sè ti ilé fi jó. Nje iwo ti ri tálákà ri? Oré mi won s’óra ju onísé mònà móná lo nígbàti won ba yá  èsó elésó lo!

Àwon méjèjì mo òbí ara won , ìná wò , won si da ojó  ìgbéyàwó. Ojó pé . Bàbá ìyàwó lo ra aso oko ati ìyàwó, oun náà lo ra aso oré oko ati  ti ìyàwó  la i jé kí wón ná kóbò nínu ìnáwó ńlá yi.

Béè  wákàtí méjì s’éhìn ni Oníwàásù so  t’oko t’ìyàwó pò ni ilé ìjósìn BoN. Adura ti gba pe omobìnrin ti n’wá oko ti ri oko bi o t’ile jé pé ojó orí ìyàwó ju ti oko lo. Sèbí bi a kò ri oun ti a fé a óò fé oun ti a rí, kò s’óko ni ìgboro. Oko t’ilè dà? Se awon onisòkòtò tínrín wònyi l’o fé fé ìyàwó l’áìnísé?. Kò si oko gidi  o jàre ,oko wà sùgbón oko sáá l’ó wà à ni  oko gbà je nsimi ló wà. Ìdí nìyí ti Bàbá omo pò repete  o jàre. A ni se ko si oko gidi. Oko iyawo yi ko ni isé béè wárápá ńyo ìyàwó l’énu ,èyí nìkan kó,ojó orí ìyàwó ju ti oko lo. Irun funfun ti bo ìyàwó l’órí opélópé wíígì àtèmóri àsírí bo irun  .Sùgbón òkú òru ni a fi eyi se. Sèbí f’orí tìí f’orí tìì ló mú kí ori àgbà pá. Bi o ti lè jé pé ará ilé ìyàwó nìkan ló mò pe aláágànná ni omo won. Sùgbón t’aló  lè so ó jàde?  Tani jéé tú àsírí s’íta?. Obè kii mì n’íkùn àgbà. Se l’énu mi ni ká ti gbó pé ìyá Baálè l’ájé tabi   ìyá Tísà kú?.

L’ójìjì ni a ri ìyàwó ti o s’ubú l’ulè ti o fi owó méjèjì gbá inú mú ti o fi  igbe b’onu   ”oro o, wón ti gun mi l’óbe o”,okùnrin kan ti o ńjo ti o sì nlèé l’owó la ri. Gbàrà ti o súbú ni onítòhún ti  pòórá bi isó. Asèkà tan t’esè m’órìn,sèbí bi oba aiyé ko ri e Oba òkè nwo e. O di dìgbàdìgbà wón gbe  ìyàwó lo  ile ìwòsàn. Bàbá ìyàwó b’arajé  , o ni eí pa omo òun yí ó ò je ìyà.

Won kò mo eni ti o gunn l’óbe béè ni .. àgó  olópá ya. Olópá bérè l’owó àwon òbí ati ojúlúmò tani a fu’ra sí, sùgbón enìkéni kò le so.

Nígbàti Dókítà se àyèwò Omolará , o rii pe ikùn rè ni òbe bà, sùgbón kò w’olé sii l’ára. L’ósè kejì a dá Omolará padà s’ilè , béè ni  olópa nse ìwádí lo.

ÀSÍRÍ ŃLÁ

Omolará wa so fun Olópa ki won kó gbogbo amóhùnmáwòrán  kámérà ti a fi si k’ólófín ilé bàbá rè jàde l’áti wo eni se isé l’áabi òhún. Béè kò s’éni ti o mò pé Omolará fi kámérà si àyíká àti inú ilé wònyí. O sì see  nítorí olè, alo k’ólóhun k’ígbe , aláfowórá ati fun ààbò nígbà àsèye rè ni.

Níbí ni àsírí ti tú. Háà àkàrà tú s’épo. A rí Okùnrin kan ti o ńfún omodékùnrin kan l’ówó tùùlù tuulu  ni ìyàrá ati obè  ti orí rè ri sooroso tí o mú féléfélé bi abe ìfárí.  A si dá   omodékùnrin kan náà yi  mò  ti o fi òbe gún ìyawo nígbàti o nl’e owó móó l’ójú  ni  agbo ti wón ńjó. Kámérà tè síwájú lati ri òré Bàbá ìyàwó ti won ńsòrò wúyé wúyé .A  si tún rí Bàbá ìyàwó ti o fi aso pelebe funfun nu èjè l’ára Omolará ti o sii fi si abé agbádá rè wo ìyèwù lo, ti o fii s’ínú igbá  ti a fi owó  eyo  di l’ára. A sì rí òré Bàbá ìyàwó nígbà tí wón ńgbé igbá yi s’ínú páálí otí , l’ati  daa l’ógbón f’ihàn  pé otí ni wón ńgbé jáde lo. Béè ìtànje  lásan làsàn rèé.

NÍ ÀGÓ OLÓPÁ

Olópá pe Bàbá ìyàwó ati òré rè. Nwón wá arákùnrin ti o gún òbe .Gbogbo won ni wón wá l’áwárí bi obìnrin se ń’wá nkan obè, sèbí àwári l’obìnrin ńwá ńkan osù rè . Okan Bàbá ìyàwó balè bi tòlótòló , o ni òun kò je gbì, s’èbí eni je gbì l’oun nkú gbì. Sùgbón okàn arákùnrin  ti o gún òbe  kò  b’alè , o nke ”kíni mo se?”. S’èbí aseburúkú o kú ara í fu. O s’èkà tán o yí’dó b’orí l’áì mò pé bi oba ayé kò rí e  Oba òkè ńwò e. Ìgbà  ti o mò pé àkàrà ti tú s’épo o ni ”Èmi kò dá se é”, s’èbí àdáse nii hun ni. Ejò tó bá d’árìn la n’fòpá pa. O  f’igbe b’onu  ó ńké ”Èmi n’ìkan kó ló mò s’óràn yi o”. Bàbá ìyàwó l’owó l’owó, sèbí oun t’owo ba se tì ilè ló ńgbé. Sùgbón kò mò pe olópá ti kò ni gba rìbá nìyí,àní olópá ti kò ni gba owo èhìn ló f’ojú kàn yìí .Béèni olópá DPO yi kò ńgba àbètélè. Kíní ká  ti wá se é é  sí?

Ní  agogo  méwá ku ìséjú méjo alé ‘l’ojó Àlàmísì ni ojú  ati esè pé ni  óófísi DPO òtèlèmúyé ni àgó olópá ni ìlú BoN ti wón si fi kámérà han gbogbo àwon ènìyàn wònyi. Àsírí tú. Àkàrà tú s’épo. Bàbá ìyàwó  fi ìka àbámò s’énu , o ńké nbá mò nbá máà se é. Sùgbón  àbámò ni í gbèhìn òrò. Òtòtòto ìlú péjo won kò ri ebo àbámò se. Bàbá ìyàwó jéwó pe oun féé tun  ètùtù olà    ró   pèlu èjè omo òun nínu aso ìgbéyàwó bi aláwo oun se ni ki oun se.

Enú ko hààà. Ìyá ìyàwó, Bàbá  oko ati ìyá oko d’ákú gborangandan. Oko ìyàwó l’anu s’ilè bi ajá mi lo páaa. 

     

Sè bí ebí eni a máá  se ni. A séè kòkòrò ti njé obì inú obì nii ígbé . Kòkòrò tíí j’ewé inú ewé ni í wà. Béè sì ni kòkòrò ti njé  èfó inú èfó ló wà. À  séè ìsàlè orò a máá  l’égbin,……( Coming out soon)

Author: Taiwo Abiodun

I am a blogger . taiwoabiodun.com and TAIWOABIODUN.BLOGSPOT.COM

2 thoughts on “Ariwó ta gèè”

Leave a Reply

Your email address will not be published.