Ìrìnàjò mi sí ìlú àwon òkú

…….OKÒ OJÚ OMI DÀNÙ , ÈMÍ S’ÒFÒ

……….MO BÓ S’ÓMI SÙRÀ!

………MO PÀDÉ ÀRÒGÌDÌGBÀ NÍ ÌSÀLÈ OMI

………MO RÍ BÀBÁ ÀTI ÌYÁ MI

…….MO SE ALÁBÁPÀDÉ  ÀWON  TÍ Ó TI KÚ NI IGBA ODÚN SÉHÌN

Nígbàti mo dé èbúté BoN mo k’áwó l’órí, mo sunkún kíkórò

OKÒ OJÚ OMI DÀNÙ , ÈMÍ S’ÒFÒ

        rédíò  èro  asòròmágbèsì   náà  ti ka ìròhìn agogo mérin ìyáléta tán , igbé ta!. Gbogbo àdúgbò kan gógó. Òfò ńlá ló sè yìí. Òrò di bi o kò lo yàgò fún mi. Àwon tí wón ní  ará , ebí àti ojúlùmò  ti o rin ìrìn àjò l’órí omi nsare kíjo kíjo o di èbúté BoN l’ati mò bóyá wón ní ènìyàn nínú àwon ti ìjàmbá náà se. Béèni wón ńpe    ènìyàn   won l’áago àgbéléwó fóònù . Ojó náà ni mo rí orísirísi  àgbéléwó fóònù bí Taná s’óbè,  Bótìnì, Pèmípadà, Owó ńro mi, Bólugi, Gbéfìlà, Gbéborùn. Ńje ìròhìn  wo  ni Oníròhìn  kà?  Oniròhìn kàá  bayi:  ” Ní òwúrò kùtùkùtù òní ìròhìn tè wá l’ówó pé  okò ojú omi   ti o ńbò l’áti  èbúté T Bobo  ti o n’lo èbúté BoN  ti o kó ogójì ènìyàn àti òpòlópò   dúkìá  d’ànù sí  agbami. Ìsèlè ńlá yi sè ni agogo méwàá òwúrò. A óò ma fi ……” .

       Nígbàti mo gbó ìròhìn yi   inú mi bàjé gidigidi. Okàn mi gbogbé. Ìbànújé so orí mi k’odò . Mo la enu s’ílè bi eni ti a puró làntì lanti mó . Kinla! , mo kígbe. Ńkò t’ilè jé ki Oníròhìn kàá tán. Báyìí ni mo múra  láti lo si   èbúté BoN.  Mo sèbí bí   isé kò bá  pé ni a kìí pe isé . Mo pe íyàwó mi ,Fèróníkà pé  àsìkò tó  lati b’áwon  se ètùtù    pa eja ńlá ti won ńpè ni  erinmilokun  ( Whale)  ti o ńda okò ojú omi wa nù ti o si ńgba òpòlópò èmí ènìyàn nígbà gbogbo .

       À séè o ye kí a má  fura , nítórí  ìfura l’òògùn àgbà  . Mo s’èbí páńsa kò fura ló fi  já  s’íná , àjà kò fura ló  fi jìn .Èmi kò fura rárá. Àní o ye ki a máa  béèrè bi ònà yióò ti ri ki à si  tun máá fi  Olúwa sáájú . Mo se àfojúdi . Mo se àsejù, àsejù sì ni baba àseté.  Òré mi mo se àsejù mo si té bi èsúúrú ti  se àsejù ti o si té l’ówó oníyán. Béèni mo té!. Sùgbón èbi mi kó nítorípé   oò te ara re nífá,  òmòràn kò ní fi ara rè joyè béè si ni abe kò lè mú títí ki o   gbé èkù ara rè.  Èmi kò bèrè ,se bi abèrè ònà kìí sìnà. Sèbí  bi òní se ri òla kò ri béè   lo ńmú kí  Babaláwo máa  d’ífá oroorún  sùgbón òrò ti yípadà kìíse oroórún mó sùgbón  l’ojójúmó ni nísisìyí. Sùgbón mo ti ń’jáde lo nkò le padà s’ílé mo , sèbí bi itó bá balè  kii padà sénu mó , ó sèèwò  . Mo  ko ìpàkó s’éhìn , mo k’ojú síwájú bi òkú Ìmàle  mo sèbí bí Mùsùlùmí òdodo bá kú Kiblah là ńkojú òkú rèé si , mo kojú sí ibi ti mò ńlo o jàre.  Jíjáde  mi kúrò níle  a séè bi mo se máa  lo àjò àrèmábò nìyen. Àséè  lílo mi  ìkehìn nìyen . Àséè àlo rámi rámi là ńri a kìí rí àbò rè. Àséè ohun ti ńbe léhìn èfà  ju òje lo . Àséè rírò ni t’ènìyàn síse ni t’Olórun  Oba . Ohun ti mo l’érò òtò sùgbón ohun tí mo bá l’óhún òtò mà ni o. L’éhìn ti mo rí eja mélo kan pa mo tèlé àwon aláwo láti se ètùtù.   

             

         MO BÓ S’ÓMI  SÙRÀ 

 Sè bí mo mòó tán , mo mòó tán ni orò fi ńgbé okùnrin  lo. Bi  a  ti    parí ètùtù tán ni a wo okò ojú omi kékeré padà si èbúté  .Bí  mo se  ńjáde kúrò nínú okò   ni esè mi  ńyò   , mo bèrè si ńdura  . Mo fi owó méjèjì mú okùn ti a so mó okò ojú omi dání. Bí àwon kan se ńgbìyànjú láti yo mí kúrò ni mo sàkíyèsí pé àwon kan ńfà mi láti ìsàlè omi béè èmi kò rí won. Ìka àtànpàkò ati  ìfábeèlá mi bèrè si se èjè níbi ti mo ti di okùn mú. Àsé bi ará ayé se ńpe ni  náà ni ará  òrun ńpe ni bí olókùnrùn ati arúgbó  sùgbón àdúrà ká  pé l’órí eèpè là   ńgbà . Òràn mi wáá  dàbí ti olókùnrùn ti ńwo àjùlé òrun òun ayé l’óòkan. Wàhálà dé, ìdààmú ba mi .Háà se oun ti ojú ńwá l’ójú ńrí . Sùrà ni owó mi j’ábó ti mo subú sínú omi .Mo dura , mo jà pìtìpìtì , mo mú  ìfòófò ojú omi ati omi d’áni àséè nkò lè gbá  won  mú. Dòòòòòò ni mò ńlo ìsàlè. Sùgbón bí mo se ńlo ìsàlè  omi mo ríi pe aso mi kò tutù, o  si dàbí ìgbàtí  éńjìnì èro òyìnbó (lift) ti ńgbé ènìyàn lò si òkè tabi ìsàlè.

MO PÀDÉ ÀRÒGÌDÌGBÀ NÍ ÌSÀLÈ OMI

Mo pàdé àrògìdìgbà ní isàlè omi

Nígbàti mo dé ìsàlè omi  mo rí obìnrin rògbòdò kan ti irun orí rè ńdán bi wúrà ti  ìrù   fàdákà  eja wà ni ídí  rè .Ojú obìnrin náà ńdán mórán mórán bi góòlù ti a sèsè yo  kúrò nínú iná alágbède .Bí  mo ti rii ni  ara mi ńgbòn,enu mi ro, jìnnì jìnnì bò mi, ara mi ségìrì mo se èyó sara  , díè ló sì kù kí ìgbònsè j’ábó ni ìdí mi. Orí mi wú  béèni  mo sì gan pa bi eni ti iná èlétíríkì  mú.

Sùgbón rírí ti o rí mi o fi mí l’ókàn balè. Nígbà náà ni ara mi wáá balè , okàn mi si tutù bí omi àmù .Inú èmi náà wáá ńdùn sèsè  bi ení  je  tété. Kíákíá mo ti ńronú  bi ngò se bá omobìnrin  náà sòrò ìfé . Háà òmùtí gbàgbé ìsé . Mo ńyò sèsè mo di aláìnírònú ará Galátíà. Mo di òbo ti o  ri ògèdè  ti o  ńfò fèrè.  Nkò rántí ibi tí mo  ti ńbò ati ibi ti mo  wà mó. Mo ńwo obìnrin yi tèrín tèrín , inú mi ńdùn, mo ti ńtò sára . Mo  ńfi ojú inú ńwo bi ngò  ti ba  se erée  yùnké yùnké . Sùgbón nígbàtí  mo rańtí ìrù fàdákà eja ìdí rè ti o ńyí lo sí òtún ati sí  òsì , nse ni nkan omokùnrin mi ti ńmì làgà lógó l’ábé aso  dúró jééé. Ìtìjú muu, ara rè balè ,ó  wò sììn  bi obè páànù. O wá súnkì  bi òkùn.  Háàà ìbèrù b’ojo mú kiní òhún  ti o fi orí jo  ejò lai tíì fi ojú kàànn. Àséè ojú inú wà lóòtó, ojú inú rírán ju  ojú òde lo. Ìtìjú bá omokùnrin mi  o sì s’áwolé lo.

MO RÍ BÀBÁ ÀTI ÌYÁ MI TI WÓN TI KÚ

Obìnrin  àrògìdìgbà yi wò mi , o sì bú s’érín nígbàti o mo èrò okàn mi, o si    wipe ” Bàbá re, Jóshúà  wa níbí. Ìyá re, Oládoyin si wà níhàhín  ti won  ńdókewè” .  Ó fùn mi ni aso kan ,o ni  ” wo   èwù yi ki o sì ko  iwájú rè si èhìn, pe orukó Bàbá re  léèméta , máse pèé ni ‘Bàbá ,tabi  ‘ìyá  tàbi ‘bùròdá’ tabi  ‘àntí’ bi o bá rí Bàbá  ati Ìyá re jòwó máse dì  wón mú. Bá won sòrò ” . Bi o se so bayi ni o sí  ilèkùn yàrá kan  mo si nwo imole niwaju mi , mo wo    inú rè lo, béè ni mo bá ara mi nínu ilé nla dídán náà ti a fi góòlù iyebíyè se òsó rè.

Mo ńwo  ìmólè níwájú mi , mo wo ilé nla dídán náà ti a fi góòlù iyebíyè se òsó rè

Ni ojú  ònà jìnnì jìnnì tún  bò mi, àyà  mi já , orí mi si wúwo  nígbàti  mo ri òpòlópò àwon ènìyàn ti wón ti kú ni igba odún séhìn. Mo dá àwon kan  mò, àwon tí ńkò dá mò si dá mi mò sùgbón won kò fi owó  kàn mi béèni ńkò jéé dáa l’ábàá l’áti fi owó tó won . Nwón nwá si òdò mi l’ókòòkan l’áti bá mi sòrò àti l’áti rán mi si àwon ènìyàn won ni ilè alààyè.

Ìwo  ònkàwéè mi yi mo rí àwon òbí re méjèjì níbè  béè ni  àwon Oba lé ní àádóta ti mo rí nínú aso oyè won . Ngò ò maa d’árúko won nínú ìwé mi ti o ńbò l’ónà.

Wéré ti  mo ri  Bàbá mi mo pèé” Bàbá! Bàbá!!” Sùgbón ko dá mi l’óhùn . Nígbàti mo dúró  fun  iséjú méédógún  ni mo  wa  rántí pe awon òbí mi ti kú. Sèbí àwon ni  àwon Akorin ko orin” L’òwùro Òjo Ajinde, t’ara t’okàn yoo pàdé …A wón ti gún s’ébúté l’ókè Òrun l’ókè òrun , ebi kò ni pa wón mo…Jèrúsálem t’Orùn, òrun mi ìlú mi ….” fún l’ódún náà l’óhùún. Sèbí  ité  ìsìnkú si ni St. Patrick’s Anglican  Church Ìjèbú -Òwò ni a sin won si .Mo tun ranti pe Àlùfáà se ‘eruku fún eruku, iyèpè fun iyèpè’ ni ibojì won nígbàti a dágbéré fun won pe ó dìgbóse.

Mo rántí pe mo gbéra sánlè l’ójó náà l’óhùn nígbàti wón ńwá erùpè bo àwon méjèjì m’ólè , b’áwo ni wón se wa se dé  isàlè omi? .Sé ànjònú ni wón ni tàbí mo ńlá àlá?. Orísirísi èrò lo wá sí okàn mi . Mo rántí pé o ti tó odún métàdínlógójì àti márùndínlógún tí àwon méjèjì ti papòdà tí wón si ti fi ilè bora bí aso .Sèbí  won a ti di egungun wóngan wòngan. Gbogbo egungun won á ti funfun ìyen ti àwon olóríburúkú asètùtù olà kó bá tíì lo kó won níbi ité .Sèbí ohun ti àwon  òpònú ati òle òdó aláìnírònú ti wón   fé ni  owó òjijì ńse l’ásìko yi ni, sèbí awon Babaláwo ìkà òun  èké lo ńrán won.

Egungun àwon òbí mi  ti di  funfun

Sùgbón mo rańtí pé  abàmì  obìnrin ìsàlè odò yi so pé  ki ńpe àwon òbí mi l’órúko. Háà èèwò , àrífín ńlá ki npe  àwon òbí mi l’órúko ?.Mo rántí esè ìwé Bíbélì to so pé ” Bòwò fún  Bàbá ati Ìyá re kí ojó re lè pé l’órí ilè ti Olúwa Olórun re  fi fun e”. Mo tún rántí olórin Oba Jùjú  Sunny Ade   tó  k’orin  pé Bàbá kò se é pààrò beni ìyá ko se é pààrò , tàbí wón pààrò won fún mi ni? .Sùgbón mo wáá rójú dájú, sè bí òdájú la fi ńwe egbò  bi béèkó egbò kò ni jiná. Mo wá a dárúko lé Bàbá mi lórí, àni mo la orúko móó l’órí ,  mo sì  pèé ”Jóshúà! , Jóshúà!! , Jóshúà!!! léèméta. Léhìn èyí ni mo ri Okùnrin arúgbó kùjèkuje kan ti kò ga tí kò sì kúrú nínú aso  kóòtù ati táì  orùn rè. Mo sì ríi ti o pá l’órí  ,  o fi  díngí   sójú, pèlù òpá ìtìlè rè ti o mú dání o si pè mi ”Taiwo! ,Taiwo!! kí lo wa se níbí?”.  Léhìn èyí ni o kojú sí mi ti o wí pé ”Omo mi l’áti odún métàdínlógójì ni mo ti kúrò n’ílé ayé. Isé ti mo ńse ni ìgbà aiyé mi náà ni mo nse níbí bi Post master . Gbogbo létà ti wón ńfi ránsé si ilè alààyè l’áti òdò mi ni wón ti ńrà sítámpù rè. Jé kí ńso fún e , bí wón se ńse l’áiyé ni won ńse l’órun ”

    Bàbá mi sòòrò    o  si fún mi ni èbùn  ó  ni ”Jòwó  máse kó egbé kégbé , máse mu otí àmupara  .Sóra fún  òré . Gba òrùka  yìi, nígbà kígbà ti o bá n’jáde n’ílé ni ki o fi sówó ,enìkéni ti o ba ńbínú re yìóò yónú si e .

           

 Bàbá  mi  ńbá mi sòrò,mo sì gbówó l’érán

”Sèbí ètùtù   ìyónú ni ewúré se ti o  ńfi ara ńnu olóde n’ílé . Sèbí  ètùtù ìyónú ni adìye se  ti o fi ńda ètù ìbon olóde nù n’ílé, sùgbón àpárò ati ìgalà kò lati se ètùtù  ìyónú  ti Babaláwo ni ki wón se l’ójó náà l’óhún  ni wón fi di  òtá  olóde  títí  di òní olónìí ” . 

   Bi Bàbá mi se ju òrùka náà si mi  ni mo pa gúúrú  sii ti mo  féé dì móó béè  ni o pòórá ,  ti ńkò ríi mó .Ìjì  ńlá kan bèrè si   jà ,léhìn eyi ni mo n’gbóhùn rè ti o wipe ”. Èèwò , àgbedò, máse dánnwò .  Báwo lo se fé dì mo mi?. Mo ti di aféfé, nítorí  nkò fe ki o fi owó kàn mi. Èmi ati ìyá re ti di ewúré jeléjelé a si  ti di àgùtàn jemòjemò ,  a si ti di òrìsà àkúnlèbo. Wo òòkán re ìwo yi o ri ìyá re níbè  o dàbò”.

Báyìí ni mo sun ekún kíkórò . Mo ké lohùn rárá pé  ” Bàbá  mi tòòtó, Bàbá  mi aiyé , Bàbá  mi òrun, Bàbá  olomo ti ko gbódò sùn .Sé bi o se máa wò mi níran rèé?. Ìyà njé mi . Àwon ìkà ènìyàn  ńlépa èmí mi nitori mo ńko nípa Olóyè ńlá kan ti àwon asekúpani fi èmi re dá ègbodò ni ilú BoN. ” . Sèbí Yorùbá bo won ni Okùnrin kìí  ké , ako igi kii s’oje, Okùnrin ké l’ojó náà l’óhùn , ako igi si se oje!

. Tekún tekún ni mo  fi mú òrùka náà ti  Bàbá mi  fún mi l’ójó náà l’óhún. Ikun imú mi ńdà .Omíjé ojú mi si nsàn bi isun omi . Ojú mi wú tepele bí eni agbón ta. Òrùka náà  wà l’ówó mi títí di òní olóníi .Ìwo ònkàwéè mi  ngóò  fi hàn ó  l’ójó ti mo bá fi òrùka náà  si ìka owó mi …..               ( Excerpts from my coming book)

Bàbá mi Jóshúà  Adépòjù Abíódún  ta téru nipa  ni 31-12-85. Ìyá mi  Caroline Oládoyin Abíódún si  je Olorun nipe ni 16-10-2007

 

Bàbá mi Jóshúà  Adépòjù Abíódún (JP)  papoda  ni 31-12-85. Ìyá mi  Caroline Oládoyin Abíódún sun ninu Oluwa ni 16-10-2007

Author: Taiwo Abiodun

I am a blogger . taiwoabiodun.com and TAIWOABIODUN.BLOGSPOT.COM

13 thoughts on “Ìrìnàjò mi sí ìlú àwon òkú”

Leave a Reply to Ebun Fadare Aderibigbe Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *