…….OKÒ OJÚ OMI DÀNÙ , ÈMÍ S’ÒFÒ
……….MO BÓ S’ÓMI SÙRÀ!
………MO PÀDÉ ÀRÒGÌDÌGBÀ NÍ ÌSÀLÈ OMI
………MO RÍ BÀBÁ ÀTI ÌYÁ MI
…….MO SE ALÁBÁPÀDÉ ÀWON TÍ Ó TI KÚ NI IGBA ODÚN SÉHÌN
Nígbàti mo dé èbúté BoN mo k’áwó l’órí, mo sunkún kíkórò
OKÒ OJÚ OMI DÀNÙ , ÈMÍ S’ÒFÒ
BÍ rédíò èro asòròmágbèsì náà ti ka ìròhìn agogo mérin ìyáléta tán , igbé ta!. Gbogbo àdúgbò kan gógó. Òfò ńlá ló sè yìí. Òrò di bi o kò lo yàgò fún mi. Àwon tí wón ní ará , ebí àti ojúlùmò ti o rin ìrìn àjò l’órí omi nsare kíjo kíjo o di èbúté BoN l’ati mò bóyá wón ní ènìyàn nínú àwon ti ìjàmbá náà se. Béèni wón ńpe ènìyàn won l’áago àgbéléwó fóònù . Ojó náà ni mo rí orísirísi àgbéléwó fóònù bí Taná s’óbè, Bótìnì, Pèmípadà, Owó ńro mi, Bólugi, Gbéfìlà, Gbéborùn. Ńje ìròhìn wo ni Oníròhìn kà? Oniròhìn kàá bayi: ” Ní òwúrò kùtùkùtù òní ìròhìn tè wá l’ówó pé okò ojú omi ti o ńbò l’áti èbúté T Bobo ti o n’lo èbúté BoN ti o kó ogójì ènìyàn àti òpòlópò dúkìá d’ànù sí agbami. Ìsèlè ńlá yi sè ni agogo méwàá òwúrò. A óò ma fi ……” .
Nígbàti mo gbó ìròhìn yi inú mi bàjé gidigidi. Okàn mi gbogbé. Ìbànújé so orí mi k’odò . Mo la enu s’ílè bi eni ti a puró làntì lanti mó . Kinla! , mo kígbe. Ńkò t’ilè jé ki Oníròhìn kàá tán. Báyìí ni mo múra láti lo si èbúté BoN. Mo sèbí bí isé kò bá pé ni a kìí pe isé . Mo pe íyàwó mi ,Fèróníkà pé àsìkò tó lati b’áwon se ètùtù pa eja ńlá ti won ńpè ni erinmilokun ( Whale) ti o ńda okò ojú omi wa nù ti o si ńgba òpòlópò èmí ènìyàn nígbà gbogbo .
À séè o ye kí a má fura , nítórí ìfura l’òògùn àgbà . Mo s’èbí páńsa kò fura ló fi já s’íná , àjà kò fura ló fi jìn .Èmi kò fura rárá. Àní o ye ki a máa béèrè bi ònà yióò ti ri ki à si tun máá fi Olúwa sáájú . Mo se àfojúdi . Mo se àsejù, àsejù sì ni baba àseté. Òré mi mo se àsejù mo si té bi èsúúrú ti se àsejù ti o si té l’ówó oníyán. Béèni mo té!. Sùgbón èbi mi kó nítorípé oò te ara re nífá, òmòràn kò ní fi ara rè joyè béè si ni abe kò lè mú títí ki o gbé èkù ara rè. Èmi kò bèrè ,se bi abèrè ònà kìí sìnà. Sèbí bi òní se ri òla kò ri béè lo ńmú kí Babaláwo máa d’ífá oroorún sùgbón òrò ti yípadà kìíse oroórún mó sùgbón l’ojójúmó ni nísisìyí. Sùgbón mo ti ń’jáde lo nkò le padà s’ílé mo , sèbí bi itó bá balè kii padà sénu mó , ó sèèwò . Mo ko ìpàkó s’éhìn , mo k’ojú síwájú bi òkú Ìmàle mo sèbí bí Mùsùlùmí òdodo bá kú Kiblah là ńkojú òkú rèé si , mo kojú sí ibi ti mò ńlo o jàre. Jíjáde mi kúrò níle a séè bi mo se máa lo àjò àrèmábò nìyen. Àséè lílo mi ìkehìn nìyen . Àséè àlo rámi rámi là ńri a kìí rí àbò rè. Àséè ohun ti ńbe léhìn èfà ju òje lo . Àséè rírò ni t’ènìyàn síse ni t’Olórun Oba . Ohun ti mo l’érò òtò sùgbón ohun tí mo bá l’óhún òtò mà ni o. L’éhìn ti mo rí eja mélo kan pa mo tèlé àwon aláwo láti se ètùtù.
MO BÓ S’ÓMI SÙRÀ
Sè bí mo mòó tán , mo mòó tán ni orò fi ńgbé okùnrin lo. Bi a ti parí ètùtù tán ni a wo okò ojú omi kékeré padà si èbúté .Bí mo se ńjáde kúrò nínú okò ni esè mi ńyò , mo bèrè si ńdura . Mo fi owó méjèjì mú okùn ti a so mó okò ojú omi dání. Bí àwon kan se ńgbìyànjú láti yo mí kúrò ni mo sàkíyèsí pé àwon kan ńfà mi láti ìsàlè omi béè èmi kò rí won. Ìka àtànpàkò ati ìfábeèlá mi bèrè si se èjè níbi ti mo ti di okùn mú. Àsé bi ará ayé se ńpe ni náà ni ará òrun ńpe ni bí olókùnrùn ati arúgbó sùgbón àdúrà ká pé l’órí eèpè là ńgbà . Òràn mi wáá dàbí ti olókùnrùn ti ńwo àjùlé òrun òun ayé l’óòkan. Wàhálà dé, ìdààmú ba mi .Háà se oun ti ojú ńwá l’ójú ńrí . Sùrà ni owó mi j’ábó ti mo subú sínú omi .Mo dura , mo jà pìtìpìtì , mo mú ìfòófò ojú omi ati omi d’áni àséè nkò lè gbá won mú. Dòòòòòò ni mò ńlo ìsàlè. Sùgbón bí mo se ńlo ìsàlè omi mo ríi pe aso mi kò tutù, o si dàbí ìgbàtí éńjìnì èro òyìnbó (lift) ti ńgbé ènìyàn lò si òkè tabi ìsàlè.
MO PÀDÉ ÀRÒGÌDÌGBÀ NÍ ÌSÀLÈ OMI
Mo pàdé àrògìdìgbà ní isàlè omi
Nígbàti mo dé ìsàlè omi mo rí obìnrin rògbòdò kan ti irun orí rè ńdán bi wúrà ti ìrù fàdákà eja wà ni ídí rè .Ojú obìnrin náà ńdán mórán mórán bi góòlù ti a sèsè yo kúrò nínú iná alágbède .Bí mo ti rii ni ara mi ńgbòn,enu mi ro, jìnnì jìnnì bò mi, ara mi ségìrì mo se èyó sara , díè ló sì kù kí ìgbònsè j’ábó ni ìdí mi. Orí mi wú béèni mo sì gan pa bi eni ti iná èlétíríkì mú.
Sùgbón rírí ti o rí mi o fi mí l’ókàn balè. Nígbà náà ni ara mi wáá balè , okàn mi si tutù bí omi àmù .Inú èmi náà wáá ńdùn sèsè bi ení je tété. Kíákíá mo ti ńronú bi ngò se bá omobìnrin náà sòrò ìfé . Háà òmùtí gbàgbé ìsé . Mo ńyò sèsè mo di aláìnírònú ará Galátíà. Mo di òbo ti o ri ògèdè ti o ńfò fèrè. Nkò rántí ibi tí mo ti ńbò ati ibi ti mo wà mó. Mo ńwo obìnrin yi tèrín tèrín , inú mi ńdùn, mo ti ńtò sára . Mo ńfi ojú inú ńwo bi ngò ti ba se erée yùnké yùnké . Sùgbón nígbàtí mo rańtí ìrù fàdákà eja ìdí rè ti o ńyí lo sí òtún ati sí òsì , nse ni nkan omokùnrin mi ti ńmì làgà lógó l’ábé aso dúró jééé. Ìtìjú muu, ara rè balè ,ó wò sììn bi obè páànù. O wá súnkì bi òkùn. Háàà ìbèrù b’ojo mú kiní òhún ti o fi orí jo ejò lai tíì fi ojú kàànn. Àséè ojú inú wà lóòtó, ojú inú rírán ju ojú òde lo. Ìtìjú bá omokùnrin mi o sì s’áwolé lo.
MO RÍ BÀBÁ ÀTI ÌYÁ MI TI WÓN TI KÚ
Obìnrin àrògìdìgbà yi wò mi , o sì bú s’érín nígbàti o mo èrò okàn mi, o si wipe ” Bàbá re, Jóshúà wa níbí. Ìyá re, Oládoyin si wà níhàhín ti won ńdókewè” . Ó fùn mi ni aso kan ,o ni ” wo èwù yi ki o sì ko iwájú rè si èhìn, pe orukó Bàbá re léèméta , máse pèé ni ‘Bàbá ,tabi ‘ìyá tàbi ‘bùròdá’ tabi ‘àntí’ bi o bá rí Bàbá ati Ìyá re jòwó máse dì wón mú. Bá won sòrò ” . Bi o se so bayi ni o sí ilèkùn yàrá kan mo si nwo imole niwaju mi , mo wo inú rè lo, béè ni mo bá ara mi nínu ilé nla dídán náà ti a fi góòlù iyebíyè se òsó rè.
Mo ńwo ìmólè níwájú mi , mo wo ilé nla dídán náà ti a fi góòlù iyebíyè se òsó rè
Ni ojú ònà jìnnì jìnnì tún bò mi, àyà mi já , orí mi si wúwo nígbàti mo ri òpòlópò àwon ènìyàn ti wón ti kú ni igba odún séhìn. Mo dá àwon kan mò, àwon tí ńkò dá mò si dá mi mò sùgbón won kò fi owó kàn mi béèni ńkò jéé dáa l’ábàá l’áti fi owó tó won . Nwón nwá si òdò mi l’ókòòkan l’áti bá mi sòrò àti l’áti rán mi si àwon ènìyàn won ni ilè alààyè.
Ìwo ònkàwéè mi yi mo rí àwon òbí re méjèjì níbè béè ni àwon Oba lé ní àádóta ti mo rí nínú aso oyè won . Ngò ò maa d’árúko won nínú ìwé mi ti o ńbò l’ónà.
Wéré ti mo ri Bàbá mi mo pèé” Bàbá! Bàbá!!” Sùgbón ko dá mi l’óhùn . Nígbàti mo dúró fun iséjú méédógún ni mo wa rántí pe awon òbí mi ti kú. Sèbí àwon ni àwon Akorin ko orin” L’òwùro Òjo Ajinde, t’ara t’okàn yoo pàdé …A wón ti gún s’ébúté l’ókè Òrun l’ókè òrun , ebi kò ni pa wón mo…Jèrúsálem t’Orùn, òrun mi ìlú mi ….” fún l’ódún náà l’óhùún. Sèbí ité ìsìnkú si ni St. Patrick’s Anglican Church Ìjèbú -Òwò ni a sin won si .Mo tun ranti pe Àlùfáà se ‘eruku fún eruku, iyèpè fun iyèpè’ ni ibojì won nígbàti a dágbéré fun won pe ó dìgbóse.
Mo rántí pe mo gbéra sánlè l’ójó náà l’óhùn nígbàti wón ńwá erùpè bo àwon méjèjì m’ólè , b’áwo ni wón se wa se dé isàlè omi? .Sé ànjònú ni wón ni tàbí mo ńlá àlá?. Orísirísi èrò lo wá sí okàn mi . Mo rántí pé o ti tó odún métàdínlógójì àti márùndínlógún tí àwon méjèjì ti papòdà tí wón si ti fi ilè bora bí aso .Sèbí won a ti di egungun wóngan wòngan. Gbogbo egungun won á ti funfun ìyen ti àwon olóríburúkú asètùtù olà kó bá tíì lo kó won níbi ité .Sèbí ohun ti àwon òpònú ati òle òdó aláìnírònú ti wón fé ni owó òjijì ńse l’ásìko yi ni, sèbí awon Babaláwo ìkà òun èké lo ńrán won.
Egungun àwon òbí mi ti di funfun
Sùgbón mo rańtí pé abàmì obìnrin ìsàlè odò yi so pé ki ńpe àwon òbí mi l’órúko. Háà èèwò , àrífín ńlá ki npe àwon òbí mi l’órúko ?.Mo rántí esè ìwé Bíbélì to so pé ” Bòwò fún Bàbá ati Ìyá re kí ojó re lè pé l’órí ilè ti Olúwa Olórun re fi fun e”. Mo tún rántí olórin Oba Jùjú Sunny Ade tó k’orin pé Bàbá kò se é pààrò beni ìyá ko se é pààrò , tàbí wón pààrò won fún mi ni? .Sùgbón mo wáá rójú dájú, sè bí òdájú la fi ńwe egbò bi béèkó egbò kò ni jiná. Mo wá a dárúko lé Bàbá mi lórí, àni mo la orúko móó l’órí , mo sì pèé ”Jóshúà! , Jóshúà!! , Jóshúà!!! léèméta. Léhìn èyí ni mo ri Okùnrin arúgbó kùjèkuje kan ti kò ga tí kò sì kúrú nínú aso kóòtù ati táì orùn rè. Mo sì ríi ti o pá l’órí , o fi díngí sójú, pèlù òpá ìtìlè rè ti o mú dání o si pè mi ”Taiwo! ,Taiwo!! kí lo wa se níbí?”. Léhìn èyí ni o kojú sí mi ti o wí pé ”Omo mi l’áti odún métàdínlógójì ni mo ti kúrò n’ílé ayé. Isé ti mo ńse ni ìgbà aiyé mi náà ni mo nse níbí bi Post master . Gbogbo létà ti wón ńfi ránsé si ilè alààyè l’áti òdò mi ni wón ti ńrà sítámpù rè. Jé kí ńso fún e , bí wón se ńse l’áiyé ni won ńse l’órun ”
Bàbá mi sòòrò o si fún mi ni èbùn ó ni ”Jòwó máse kó egbé kégbé , máse mu otí àmupara .Sóra fún òré . Gba òrùka yìi, nígbà kígbà ti o bá n’jáde n’ílé ni ki o fi sówó ,enìkéni ti o ba ńbínú re yìóò yónú si e .
Bàbá mi ńbá mi sòrò,mo sì gbówó l’érán
”Sèbí ètùtù ìyónú ni ewúré se ti o ńfi ara ńnu olóde n’ílé . Sèbí ètùtù ìyónú ni adìye se ti o fi ńda ètù ìbon olóde nù n’ílé, sùgbón àpárò ati ìgalà kò lati se ètùtù ìyónú ti Babaláwo ni ki wón se l’ójó náà l’óhún ni wón fi di òtá olóde títí di òní olónìí ” .
Bi Bàbá mi se ju òrùka náà si mi ni mo pa gúúrú sii ti mo féé dì móó béè ni o pòórá , ti ńkò ríi mó .Ìjì ńlá kan bèrè si jà ,léhìn eyi ni mo n’gbóhùn rè ti o wipe ”. Èèwò , àgbedò, máse dánnwò . Báwo lo se fé dì mo mi?. Mo ti di aféfé, nítorí nkò fe ki o fi owó kàn mi. Èmi ati ìyá re ti di ewúré jeléjelé a si ti di àgùtàn jemòjemò , a si ti di òrìsà àkúnlèbo. Wo òòkán re ìwo yi o ri ìyá re níbè o dàbò”.
Báyìí ni mo sun ekún kíkórò . Mo ké lohùn rárá pé ” Bàbá mi tòòtó, Bàbá mi aiyé , Bàbá mi òrun, Bàbá olomo ti ko gbódò sùn .Sé bi o se máa wò mi níran rèé?. Ìyà njé mi . Àwon ìkà ènìyàn ńlépa èmí mi nitori mo ńko nípa Olóyè ńlá kan ti àwon asekúpani fi èmi re dá ègbodò ni ilú BoN. ” . Sèbí Yorùbá bo won ni Okùnrin kìí ké , ako igi kii s’oje, Okùnrin ké l’ojó náà l’óhùn , ako igi si se oje!
. Tekún tekún ni mo fi mú òrùka náà ti Bàbá mi fún mi l’ójó náà l’óhún. Ikun imú mi ńdà .Omíjé ojú mi si nsàn bi isun omi . Ojú mi wú tepele bí eni agbón ta. Òrùka náà wà l’ówó mi títí di òní olóníi .Ìwo ònkàwéè mi ngóò fi hàn ó l’ójó ti mo bá fi òrùka náà si ìka owó mi ….. ( Excerpts from my coming book)
Bàbá mi Jóshúà Adépòjù Abíódún ta téru nipa ni 31-12-85. Ìyá mi Caroline Oládoyin Abíódún si je Olorun nipe ni 16-10-2007
Bàbá mi Jóshúà Adépòjù Abíódún (JP) papoda ni 31-12-85. Ìyá mi Caroline Oládoyin Abíódún sun ninu Oluwa ni 16-10-2007
O gb’iyanju pupo. Mini o lol see ni ilu awon oku ?
E se Ma. Mo lo si ilu awon oku lati lo wo bi won se nse lohun ni o
O kare o Arole D.O FAGUNWA.
A ngbadun itan na gaani o. K’ẹmi Ola o gun o.
E se a dupe o. Baba kee pe fun wa o
Mó gbádun àló yí gáání.
Ękú kitá kitá.
A dupe , e seun ganni
Ha Bobo T, iwe yi ti dun ju. Mo n foju sona lati ka apakeji .
E seun mi o
Baarohin Extraordinarie! Akagbadun ni itan yi. Omo Yoruba, e gbe laruge. E pin in, Share it. Ire o! Kabiti.
A dupe oga mi. E bawa gbe laruge o
Hun! Akiika! Ogbon ori e ju ti ijapa Ologbon ewe lo. O ku akitiyan. Ise takuntakun ni o se
E seun mi o. Ki e fi ojusona l’ati ka iwe mi o.
A ki ka!. E ku ogbon ati laakaye. Mo ma foju sona fun apa keji irin ajo yi.